Timothy Adegoke: Olugbade ní lóòtọ́ọ́ ní Ramon Adedoyin dìde sí òun nílé ẹjọ́ pé ọ̀tá òun yóò kú

Timothy Adegoke ati Femi Falana

Ìdí rè é tí a fi gba Femi Falana gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò ikú Timothy

Timothy Adegoke : Ẹbí olóògbé sọ pé àwọn ọmọ Naijiria ló dá owó tí Falana kọ̀

Olugbade Adegoke, to jẹ ẹgbọn fun akẹkọọ Fasiti Obafemi Awolowo, Timothy Adegoke, to ku sile ìtura kan n'ilu Ile-Ife, ti sọ idi ti wọn fi gba Femi Falana gẹgẹ bi agbẹjọro tuntun.

Ẹbi Timothy pe oludasilẹ ile itura Hilton Hotels and Resort, Ramon Adedoyin ati awọn òṣìṣẹ́ rẹ mefa lẹjọ fun ipa ti wọn ko ninu iku ọmọ wọn.

Ọjọ kẹfa, oṣù Kọkanla, ọdun 2021 ni Timothy ku, ti ile itura naa si sin oku rẹ lai sọ fun ẹbi tabi ọlọpaa.

Àkọlé fídíò, Timothy Adegoke: Màmá olóògbé ní ògó ilé àwọn ni wọ́n pa, ikú rẹ̀ kò gbọdọ̀ já sásán

A ko yọ Agbẹjọro wa tẹlẹ kuro ninu ẹjọ Timothy, yoo maa sisẹ pọ pẹlu Femi Falana ni:

Ọgbẹni Gbade Adegoke, sọ fun BBC Yoruba pe kii ṣe pe awọn paarọ agbẹjọro to n ṣojú ẹbi tẹlẹ ninu igbẹjọ iku Timothy amọ yoo pawọpọ lati sisẹ pẹlu agbẹjọro tuntun naa ni.

O ni awọn gba Femi Falana ko le fi ìmọ̀ kun ìmọ̀ gẹgẹ bi agbẹjọro agba SAN, pẹlu awọn to wa nilẹ tẹlẹ ni nitori pe "ẹjọ nla ni ẹjọ iku Timothy".

"Awọn eeyan lo n gba wa nimọran pe ka lọ gba agba amofin SAN ko lewaju ẹjọ naa, ko maa baa si madaru lori rẹ nitori ‘International case’ ni.

Agbẹjọro wa to bẹrẹ ẹjọ naa sa ipa tiẹ naa o, mo ki, mo yiin, koda mo n gba adura fun amọ Falana ni yoo lewaju, ti oun yoo tẹle agba amofin naa.

Ohun ta fẹ ni idajọ ododo, o si gbọdọ fi idi mulẹ lori ẹjọ iku Timothy yii."

Ramon Adedoyin koju mi nile ẹjọ pe ọta mi maa ku ni:

Olugbade Adegoke tẹ siwaju ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC pe se ni ogbontarigi olujẹjọ lori ẹjọ naa, Ramon Adedoyin n dunkooko mọ oun lori igbẹjọ naa.

O salaye pe se ni Adedoyin duro niwaju ile ẹjọ, to si ni ọta oun maa ku ni.

Idi ree ti mo se n rọ gbogbo ọmọ Naijiria pe ki wọn gba mi, a ko si gbọdọ maa woran nipa rẹ.

"Awọn ọlọpaa kuku wa nibẹ nigba to n sọ ọrọ naa amọ wọn ko se ohunkohun nipa rẹ.

Ẹni ti to wa ni atimọle amọ ti wọn fi ọkọ ọlọyẹ jiibu gbe wa sile ẹjọ, koda, ọkọ ara rẹ ni nitori a se iwadi nipa ẹni to ni mọto naa pẹlu nọmba ara rẹ, a si ri pe Adedoyin funra rẹ lo ni.

A dupẹ fun Ọlọrun sa pe Baba Falana ti tẹwọgba ẹjọ naa, a si gbadura pe Ọlọrun yoo lo wọn lati gba idajọ nla fun wa."

O sọ pe awọn iriri ti Falana ni pọ gẹgẹ bi agba agbẹjọro.

Àkọlé fídíò, Àwọn òṣìṣẹ́ Adedoyin jẹ́wọ́ fún wa pé àwọn pa àbúrò mi, ọ̀gá Adedoyin sì mọ̀ síi - Ẹ̀gbọ́n Timothy Adegoke

Ṣe lootọ ni ẹbi Timothy Adegoke fi miliọnu mẹtadinlogun lọ Femi Falana?

Alagba Gbade ṣalaye fun BBC pe kii ṣe pe ẹbi fẹ fun Femi Falana ni owo.

O ni awọn ọmọ Naijiria lo n pariwo pe iye to ba fẹ na awọn, awọn setan lati san ki idajọ ododo le wa, kawọn si lọ gba agbẹjọro to ti gba oye amofin agba SAN.

"Amọ nigba ta kan si baba Falana, wọn ko tii ba mi sọ ohunkohun nipa iye ti wọn fẹ gba lori ẹjọ yii tabi pe wọn fẹ gba owo.

Amọ awọn ọmọ Naijiria lo n pariwo pe iyekiye ti wọn ba fẹ gba, awọn setan lati san owo naa"

Wọn si ti n da owo naa. jọ ṣugbọn Falana kọ owo naa."

Femi Falana funra rẹ lo pe mi pe oun yoo se ẹjọ naa lai gba kọbọ:

Olugbade sọ iwaju pe Femi Falana funra rẹ gan lo n pe oun lori ẹjọ Timothy ati bo se n lọ, paapaa nigba ti wọn gbọ igbe awọn ọmọ Naijiria.

"Baba funra wọn gan ni wọn pe mi nigba ti wọn gbọ ohun tawọn ọmọ Naijiria n se, o ni Olugbade awọn ko ni gba owo lọwọ wa, ẹ ma sare kiri.

Owo ti awọn eeyan ba da, ẹyin ẹbi oloogbe, ẹ gbaa, kẹ maa fi se nnkan miran tori ẹni to n tọju yin lo ti ku yii.

Ti Timothy ba jẹ ọmọ inu mi, maa sa gba idajọ ododo fun."

Àkọlé fídíò, Plights of Widows in Nigeria: Abosede Ilori ní N16,000 ni òun ń gbà fi tọ́jú ọmọ méjì

Ile ẹjọ wo ni igbẹjọ àwọn afurasi to pa Timothy ti n waye?

Ṣaaju asiko yii, ile ẹjọ ti wọn ti n gbọ ẹ̀sùn naa ko fii bẹẹ han.

Amọ, Ogbẹni Gbade sọ fun BBC pé ọjọ kẹjọ, oṣù Keji, ni igbẹjọ iku Timothy Adegoke yoo tẹsiwaju nile ẹjọ giga to wa ni Gudu, ni agbegbe Apo n'ilu Abuja.

Iroyin ti a gbọ kẹhin lori igbẹjọ naa ni pe àwọn ẹbí ati agbẹjọro wọn n fẹ ki adajọ taari ẹjọ naa si ilu Osogbo, nipinlẹ Osun ni wọn igba to jẹ pe ibẹ ni iṣẹlẹ ti ṣẹ.

Alagba Gbade sọ pe ireti àwọn ni pe ile ẹjọ yoo gba ki wọn gbọ ẹjọ naa.

Amin iyasọtọ kan
Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, Timothy Adegoke/Facebook

Femi Falana di agbẹjọ́rò fún ẹbí Timothy Adegoke

Saaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe mọlẹbi akẹ́kọ̀ọ́ Fasiti Obafemi Awolowo, Timothy Adegoke, ti gba agba agbẹjọro, Femi Falana, lati soju wọn nile ẹjọ́.

Ninu kẹta kan ti BBC ri, ni ẹgbọn oloogbe, Olugbade, ati iyawo oloogbe, ti biwọlu u ni ọjọ kẹta, oṣù Keji, pe awọn ti gbà pe ki Falana ṣe agbẹjọro fun ẹbi wọn ninu ẹjọ́ to n lọ lori bi ọmọ wọn ṣe ku si ile ìtura Hilton to wa ni ilu Ile-Ife.

Wọn ni awọn ni igbagbọ to kún ninu Falana gẹgẹ bi ongbotagi agbẹjọro, pẹlu ireti pe awọn yoo ri idajọ ododo gba lori iku ọmọ wọn.

Bakan naa, ninu ọrọ ti ẹ naa, ileesẹ Amofin Falana, sọ pe ọ̀fẹ́ ni oun yoo soju ẹbi naa nile ẹjọ́, lai gba ohunkohun.

Ṣáájú ni a ti gbe iroyin jade lori bi akẹkọọ naa ṣe kú ni ọna to mu ifura dani, si ile itura Hilton Hotels and Resorts to wa ni ilu Ile-Ife.

Iwe ti ẹbi Adegoke fi gba Femi Falana bii agbẹjọro rẹ

Oríṣun àwòrán, Olugbade Adegoke

Ki lo ti sẹlẹ sẹyin:

Akẹẹkọ oye imọ ijinlẹ keji ni Timothy Adegoke, idanwo lo si lọ ọ ṣe to fi gba yaara si ile ìtura naa lọjọ kẹfa, oṣù Kọkanla, ọdun 2021.

Sugbọn, aṣiri pada tú pe awọn alamojuto ile itura naa sin oku rẹ lai sọ fun ẹbí rẹ tabi awọn ọlọpaa.

Lẹyin ti asiri tu ni ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, ti gbe oludasilẹ ile itura, Rahmon Adedoyin, ati òṣìṣẹ́ rẹ mẹfa lọ si ile ẹjọ giga nilu Abuja.

Wọn fi ẹsun kan Adedoyin pe o sin oku lọna ti ko tọ, o yọ ẹ̀rọ ayaworan CCTV ile itura naa lati pa ẹri rẹ, o tun pa orukọ Timothy rẹ ninu iwe akọsilẹ ile itura naa.

Ẹsun ipaniyan, iwe yiyi ati igbimọpọ ni wọn fi kan awọn to kù.

Ọmọ rẹ ọkùnrin to jẹ oludari ile itura naa ti sá lọ.

Àkọlé fídíò, Plights of Widows in Nigeria: Abosede Ilori ní N16,000 ni òun ń gbà fi tọ́jú ọmọ méjì