Èsì rèé tí Mo Abudu fọ́ ní ìdáhùn sàwọn tó sọ pé o torí owó ní ìbálòpọ̀ pẹlú àwọn olóṣèlú Nàìjíría

Oríṣun àwòrán, MO Abudu/Instagram
"Mi o le ṣe aṣiṣe ti yoo tabuku orukọ mi tabi ti yoo mu idojti ba mi lọdọ awọn ọdọ ''
Gbankọgbi ọrọ ree ti ilumọọka onisinima ati gbajumọ ori amounmaworan nii, Mosunmọla Abudu sọ ni idahun sawọn to ni o n tori owo ni ibalopọ pẹlu awọn oloṣelu.
Ni ipari ọdun 2021 ni awọn akọroyin kan gbe iroyin jade pe Mo Abudu n tori owo ati ipo ni ibalopọ pẹlu awọn to wa nipo ati oloṣelu.
Iroyin naa tun sọ pe awọn wọnyi n gbe iṣ akanṣe nla fun ṣugbọn Mo ko sọrọ si ọrọ yi lati igba naa.
- Wo ọmọ Nàìjíríà mẹ́fà tí ayélujára sọ di ìlúmọ̀ọ́ká
- Fídíò ìbálòpọ̀ tó lu jáde nípa olórin Tiwa Savage, èsì ọlọ́rọ̀ gangan rèé
- Nkechi Blessing ò lè fẹ̀sùn ibálòpọ̀ láti gba "role" kàn mí láyé! Tó bá dán an wo... - Damola Olatunji
- Ọ̀dọ́bìnrin, ẹ ṣọ́ra! Ìbàlòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin kìí ṣe ìfẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ kọ́ ni ìbálòpọ̀ - Genevieve Nnaji
- Wo ìdí méje tí olólùfẹ́ rẹ fi le kọ ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ

Oríṣun àwòrán, Chude Jideonwo/Instagram
Amọ bayi o ti wa fesi ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu Chude Jideonwo to si ni ọrọ yi ko tu irun kankan lara oun.
O ni ohun to j oun logun ni awọn ọdọ to n wo oun gẹgẹ bi awokọṣe ati pe o ṣeeṣe ki wọn gba ọrọ yi gbọ.
O ni ''Mo maa n gbọrọ si maami lẹnu daada. Wọn si ni laakaye pupọ.Wọn a maa sọ fun mi pe ki n fiwọn silẹ, ko si ẹni to mọ ọna tomi gba wọ inu agbọn''
''Tori naa mi o ni fakoko mi ṣofo lati maa fi ara mi dọgba awọn to n sọrọ nipa mi''
O tẹsiwaju pe ''awọn to mọ mi, wọn mọ mi daada, ẹnikẹni to baa n sọ isọkusọ nipa mi ko mọ mi daada ni yẹn''
Koda o sọ pe ''awọn eeyan kan a tun ,maa pemi lori ago lati mọ ohun top ṣẹlẹ. Mo si maa n dawọn lohun pada pe'ṣẹ gbadun ṣha?' ''
Oludari ati alaṣẹ ileeṣẹ fiimu EbonyLife sọ fun Chude pe awọn ọrọ ahesọ yi jẹ ohun to fọwọ kan ni lẹmi.
O fi kun ọrọ rẹ pe ọwọ oun di lasiko yi paapa pẹlu iṣẹ nla ti oun n ṣe pẹlu Netflix.
Ni idahun si ibeere pe bawo lo ṣe n ri awọn iṣẹ nla wọnyi gba, o fesi pada pe''Mi o duro soju kan kawọn naa si mura si ahesọ ọrọ wọn.''
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ''Nileeṣẹ wa, nkan bi iṣẹ akanṣẹ ọgbọn lo wa lọwọ wa pẹlu ileeṣẹ Netflix ati ileeṣẹ Will Smith to fi mọ Sony ati awọn akanṣe iṣẹ mii''
Ta ni Mo Abudu?

Oríṣun àwòrán, MO Abudu/Instagram
Mosunmola Abudu, ti ọpọ m si Mo Abudu jẹ ọmọ Naijiria ti a bi si ilẹ Gẹẹsi.
Ondo lawọn obi rẹ ti wa to si jẹ onifiimu ati gbajumọ sọrọ sọrọ ori amounmaworan.
O di ilumọọka pẹlu eto rẹ kan torukọ rẹ n jẹ ''Moments with Mo'' ko to darapọ mọ eto ''The Debaters'' ati fiimu ti akọle rẹ n jẹ ''Fifty''.
Wọn ṣe afihan ''Fifty'' ni ajọdun ere fiimu London gẹgẹ bi ere ti Naijiria mu wa sibi ayẹyẹ naa.
Mo Abudu ṣe awọn iṣẹ nla miran eyi to mu ki wọn fi orukọ rẹ sinu akọsilẹ awọn gbajumọ obinrin mẹẹdọgbọn lagbaye lagbo amounmaworan.















