Oyo APC: Omodewu ní kò ṣeéṣe kí wọn gbé òun relé ẹjọ́, àwọn ní yóò gbàjọba lọ́wọ́ PDP l‘Oyo
Lọwọlọwọ bayii, ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ipinlẹ Ọyọ ti pin si igun meji nitori awuyewuye ti o rọ mọ ẹni ti ipo alaga ẹgbẹ naa tọ si.Ṣé kìí ṣe pé wàhálà míì tún n rúgbó bọ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC Oyo?
Bi igun kan ṣe n ja fun Isaac Ọmọdewu ni igun mii n pariwo wi pe Alagba Abu Gbadamọsi ni iṣakoso naa tọsi.
BBC Yoruba ṣe abẹwo si igun mejeeji lati tu iṣu de isale ikoko ọrọ naa. Gbogbo wọn si sọrọ, ilẹ kun.
- Ìjọba àpapọ̀ yọwọ́ kúrò nínú ẹjọ́ tó ń bá Rahmon Adedoyin àtàwọn afurasí míì ṣe lórí ikú Adegoke
- Báméjì lọ̀rọ̀ Sunday Igboho lè já sí bí ó bá yanjú ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú Benin republic - Abubakar Malami
- Bí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ṣe ń wáyé lọ́wọ́ ní Abuja, Femi Falana ń bèèrè pé kí ọ̀gá ọlọ́pàá dá ẹjọ́ padà sí Osun
- "Ọ̀nà àtijẹ lára Nàíjíríà ní orílẹ̀èdè Benin ń wá tó ṣe fi oṣù mẹ́fà kún àhámọ́ Sunday Igboho"
- Ọgá ọlọ́pàá kìlọ fàwọn ọmọ iṣé rẹ tó yan ṣọ́ọ̀ṣì lilọ láàyò jù iṣẹ́ lọ,ẹ gbọ́ ohun tó sọ
- Wo ọ̀nà mẹ́ta tí obìnrin le gbà dènà òórùn ní tọjú ojú ara - Dayo Amusa
- Femi Falana kò gba kọ́bọ̀ fún ìgbẹ́jọ́ Timothy Adegoke àmọ́ aráàlú ń dáwó jọ - Ẹ̀gbọ́n olóògbé
Awọn alakoso APC ni Abuja ti gbàbọ̀dè ní wàhàlà fi wa ni Oyo - Ayo Adeseun
Ẹni akọkọ ti o ba wa sọrọ l'ọjọ Aje ni ọkan lara awọn agba ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Ayọ Adeṣeun.
Adeṣeun ṣe alaye ọrọ wi pe rọgbodiyan to n lọ lọwọ ninu ẹgbẹ oṣelu naa ti bẹrẹ lati inu iṣẹjọba gomina ana n'ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi.
O ni ede aiyede naa lo si mu ki ẹgbẹ oṣelu naa padanu ipo gomina ati ipo sẹnetọ ti wọn lero pe yoo waye nipasẹ Ajimọbi.
Sẹnetọ naa tẹsiwaju wi pe lẹyin ijakulẹ to waye ninu eto idibo ti o kọja ni awọn alakoso ẹgbẹ naa da si ọrọ aigbọra ẹni ye to n waye ninu ẹgbẹ naa, ti wọn si pẹtu si gbogbo ẹni to n fi apa janu lati fi aye gba alafia.
Ọna èrú ni Isaac Omodewu fi di alaga APC l‘Oyo:
O ni ninu iṣọkan ti ẹgbẹ naa wa ni awọn kan tun ti lẹdi apo pọ mọ awọn alakoso ẹgbẹ oṣelu naa lati ilu Abuja, ti wọn si fi ọgbọn alumọkọriyi yan Isaac Ọmọdewu gẹgẹ bii alaga, tako ipinnu ati ilana antẹle ẹgbẹ.
Adeṣeun ti o fi idi ọrọ mulẹ pe ni ọpọlọpọ igba ni oun ati awọn aṣoju ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Ọyọ ti kan sawọn alakoso nilu Abuja lori ọrọ naa, o ni pe gbogbo idarudapọ to n ṣẹlẹ ni ko se lẹyin awọn alakoso ẹgbẹ naa ti wọn gba ibọde.
O ni ti wọn ba si kọ lati gbe igbesẹ ti o tọ ki o to pẹju, o ṣeeṣe ki wọn tun padanu ninu eto idibo to n bọ lọna.
Adeṣeun ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ lo dibo yan Alagba Abu Gbadamọsi gẹgẹ bi i alaga, ṣugbọn madaru ti awọn alakoso ẹgbẹ naa n ṣe lati ilu Abuja lo ṣokunfa bi wọn ṣe kọ lati kede esi idibo meji ọtọọtọ to waye lati yan awọn alakoso tuntun nipinlẹ Ọyọ.
Asọdun ni pe wọn fẹ gbe mi lọ sile ẹjọ, awa APC la gba ijọba lọwọ PDP l‘Oyo:
Bakan naa, Họnọrebu Isaac Omodewu ti o tẹwọgba iwe ẹri gẹgẹ mo yege gẹgẹ bi i alaga ẹgbẹ oṣelu APC ba BBC Yoruba sọrọ.
Ọmọdewu ni bi eeyan meji ba n jijadu nnkan ẹyọ kan, ti o wa ja mọ ẹni kan ṣoṣo lọwọ, dandan ni ki enikeji fi apa janu.
O ni a ko le fẹ iru ede aiyede naa ku, ṣugbọn fun igba diẹ ni. O tẹsiwaju wi pe lai pe lai jina, gbogbo rọgbodiyan naa ni yoo dopin ti ẹrin yoo si tun pa ẹkẹ gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa.
Ọmọdewu ni baba ni Alagba Abu Gbadamọsi jẹ si oun ninu oṣelu. O ni asọdun ọrọ ni ohun ti awọn eeyan kan n gbe poyi ẹnu pe Gbadamọsi yoo gbe oun lọ si ile ẹjọ.
O fi kun ọrọ rẹ pe baba ko le gbe ọmọ rẹ lọ si ile ẹjọ.
Ọmọdewu ni ohun ti gbogbo aye yoo fi mọ pe ija ti pari ninu ẹgbẹ oṣẹlu APC ni pe ẹgbẹ naa yoo gba ijọba lọwọ ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo to n bọ lọna.

Ipò alága n da omi àlàáfíà ẹgbẹ́ APC rù l'Oyo

Oríṣun àwòrán, Oyo APC
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe wahala miran tun ti n rugbo bọ ninu ẹgbẹ́ oselu All Progressives Congress, APC, nipinlẹ Oyo.
Eyi ko ṣẹyin bi awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan ṣe n binu si iyansipo Ọgbẹni Ajiboye Omodewu gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ́ APC nipinlẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti awọn eekan ẹgbẹ fi sita lẹyin ipade ti wọn ṣe lọjọ Aiku, ni wọn ti sọ pe iyalẹnu lo jẹ pe olu ile ẹgbẹ APC n'ilu Abuja fun Omodewu ni iwe ẹri gẹgẹ bi alaga lai jẹ pe ipagọ ẹgbẹ́ kankan waye.
- Ìdìbò abẹ́nú APC Oyo parí àmọ́ òjò ẹ̀hónú ń rọ̀ láàrin igun tó ń bínú
- "Àwọn tó fẹ́ gbé àpótí ìbò ló ń da ẹgbẹ́ òṣèlú APC rú ni ìpínlẹ̀ Oyo"
- PDP Oyo sọ̀rọ̀ lórí pé Seyi Makinde ń lọ sẹ́gbẹ́ APC
- Bí ẹ bá tó bẹ́ẹ̀ ẹ pàdé mi l'Òjé- Makinde; Wọ́n ń tàn Ẹ́ bí àbẹ́là- APC
- Ìjà ìgboro da ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ rú ní ìpínlẹ̀ Oyo, àjọ OYSIEC fagilé ètò ìdìbò ní Ido
Ninu atẹjade naa ti àwọn eeyan bi Sẹnetọ Ayo Adeseun, Sunday Dare, Adebayo Shittu, Olufemi Lanlehin, Adebayo Adedibu, Soji Akanbi ati awọn miran.
Wọn sọ pe gbogbo agbára to wa labẹ ofin ni àwọn o fi ri daju pe Alhaji Adejare Gbadamosi ti ọpọ ọmọ ẹgbẹ da pada sipo alaga, di alaga.
"Ewu nla ni iyansipo Omodewu ti eeyan perete fọwọ si, jẹ fun ẹgbẹ APC nipinlẹ Oyo, ti yoo si yọri si ijakulẹ lasiko idibo."
Kilo fa awuyewuye lori ipò alaga APC nipinlẹ Oyo?
Ọgbọnjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021 ni ipagọ ẹgbẹ́ waye ni papa ìṣeré Lekan Salami n'ilu Ibadan.
Lara nkan to waye ni idibo alaga ẹgbẹ́.
Ṣùgbọ́n ni ọjọ kẹrin, osu Kọkanla, nibi ipade kan to waye ni Akọwe gbogbogboo ẹgbẹ́ naa ti sọ pe àṣìṣe ni ipagọ naa.
Awijare rẹ ni pe APC nipinlẹ Oyo ṣe ipagọ lai sọ fun alaga gbogboogbo tabi gba àṣẹ lọwọ rẹ.
Nibẹ naa si ni wọn ti fẹnuko pe ki eto idibo waye.
Àwọn agba ẹgbẹ́ to n binu bayii sọ pe Alhaji Gbadamosi ni àwọn dibo yan nibẹ.
Ṣùgbọ́n olu ile ẹgbẹ lo fun Ọgbẹni Omodewu ni iwe ẹri gẹgẹ bi alaga.
Eyi si lo mu ki awọn ti ko faramọ ọ sọ pe awọn ko ni i gba.
Ati pe gbogbo ọna ni awọn o gba lati da ẹni ti ọpọ ọmọ ẹgbẹ́ n fẹ pada sipo.




















