Kenya National Park Fire: Ọ̀pọ̀ awọn ẹranko tíjọba kó pamọ́ ní ọgbà ẹranko ló wà nínú ewu

Awọn eeyan to n pa ina to suyọ

Oríṣun àwòrán, Samuel Ihure

Awọn alasẹ ni orilẹede Kenya ti kede pe ọwọ awọn ti ka ida aadọrun ninu ọgọrun ina to jo ọgba ẹranko Aberdares ati igbo ọba ni aarin gbungbun orilẹede Kenya.

Awọn osisẹ panapana atawọn araalu ni wn ti n tiraka lati pa ina alagbara ọhun lati ọjọ Satide.

Iroyin kan to kọkọ jade nigba ti isẹlẹ ọhun bẹrẹ o seese ko jẹ pe ọwọ awọn eeyan kan to fẹ ba dukia ijọba jẹ ni isẹlẹ ina naa ti waye.

Amọ ijọba Kenya ti kede pe oun ti gbe igbimọ oluwadii kan kalẹ lati tan ina wadii ohun to fa isẹlẹ ijamba ina naa.

Àkọlé fídíò, Wo aburú àti ìpalára tí òògùn olóró Kush tuntun yí n ṣé ní Sierra Leone

O le ni ẹgbẹta eeka ilẹ oko to ti sofo danu nitori ijamba ina naa, eyi to tun n dunkooko iku ati ewu nla mọ awọn Erin ti wọn n daabo bo.

Bakan naa ni awọn ẹranko ibẹru mii ti wọn ko pamọ wa lọwọ ewu ina bayii.