Sunday Igboho: Sokoti ní ọmọ Yoruba ló ń tú àṣíri Igboho fún àwọn ọ̀tá rẹ̀, kìí ṣe ojú lásán

Oríṣun àwòrán, naijaexaminer
Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Adewale Abdulrasak Sokoti, ti ọpọ mọ si Sokoti Alagbede ti sọ pe bo tilẹ jẹ pe Alaafin ti ṣe irubọ lati pa epe ti Aole ṣẹ fun iran Yoruba rẹ, sibẹ, epe naa ṣi n ja nilẹ.
Sokoti lo fi ọrọ naa lede lasiko to n kopa lori eto ori redio kan, Ayekootọ pẹlu Yinka Agboola, lẹyin ti wọn fi ṣikun ofin mu Oloye Sunday Igboho lorilẹ-ede Benin Republic.
O ni pupọ ninu awọn ọta Sunday Igboho lo wa lati ẹya Yoruba funra rẹ, ati pe awọn ti ko fẹ ki ala Sunday Igboho ṣẹ lori ọrọ Yoruba Nation, lo jẹ ọmọ Yoruba, paapaa awọn to wa loke okun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Igboho kò gbọdọ̀ padà sí Nàíjíríà, Benin Republic ẹ tú u sílẹ̀ kó lè lọ gbá ''Asylum" ní Germany- Joe Okei-Odumakin
- Àjọ Anti Narcotic Cell ní India ti fẹ̀sùn kan Ndubuisi ọmọ Nàìjíríà kan pé ó gbé Cocaine wọ Mumbai
- Ọ̀rọ̀ tí Oluwo sọ ní Yidi Ileya pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Igboho kò kan òun, kò dára rárá - Olùwọ́de
- 'Sunday Igboho kò yojú sílé ẹjọ́ ní Cotonou, àtìmọ́lé ló ṣì wà'
- Sunday Igboho kìí ṣe ‘Terrorist’, ẹ fi sílẹ̀ ní àhámọ́ - Àwọn Olùwọ́de faraya
- "A kò sinmi lórí ọ̀rọ̀ Yoruba Nation, Sept 14 lá yọjú sí United Nation"
- Amotekun àtàwọn jàndùkú kọlu ara wọn ní Ibadan, èèyàn méjì kú lọ́jọ́ Ileya
Gẹgẹ bii ohun ti Sokoti sọ, Igboho ti sọ awọn ọmọ Yoruba ji lori ẹtọ wọn lati da duro gẹgẹ bii orilẹ-ede, ṣugbọn awọn Yoruba naa lo n bẹgi dina akitiyan rẹ.
O ni "Awọn eeyan wa naa lo n dalẹ Igboho, awọn to sun mọ bii iṣan ọrun, awọn to n ba tọwọ bọnu awo kan naa lo n tu aṣiri rẹ fun ọta."
"Gẹgẹ bi mo ṣe sọ tẹlẹ, awọn to wa loke okun ṣi maa bu mi lori ọrọ ti mo n sọ yii, ṣugbọn ko dun mi, awọn eeyan naa lo n bu awọn ori ade wa, ko si ṣeeṣe ki ẹni ti ẹ ti sọrọ abuku si sowọpọ pẹlu fun ija ominira kankan."
Sokoti tẹsiwaju pe "O dabi pe epe ti Aole ti ṣẹ fun iran Yoruba, lo ṣi n ja wa titi di akoko yii."
"Lootọ ni baba mi Alaafin sọ fun mi nigba kan ri pe awọn ti ṣe etutu lati wẹ epe naa danu, ṣugbgọn o dabi pe ko tii tan nilẹ."
Gbajumọ oṣere ọhun sọ siwaju si pe, epe naa ni ko jẹ ki awọn igbesẹ kan ṣeeṣe fun iran Yoruba, eyiti ko le jẹ ki imọ wọn ṣọkan.
O ni ti awọn ọmọ Yoruba kan ba n gbero lati tu nnkan ṣe, awọn ọmọ Yoruba mii lo n maa da irufẹ eto bẹẹ ru, ṣugbọn kii ṣe oju lasan.
Lori ọrọ Yoruba Nation, Sokoti sọ pe kii ṣe ohun to buru ti ẹya Yoruba ba sọ pe awọn fẹ da duro, amọ imọ Yoruba ni lati ṣọkan, awọn ọba alaye si ni lati ṣaaju.
O pari ọrọ rẹ pe awọn to n ṣiwaju ijijagbara Yoruba Nation ni lati bẹ awọn ori ade lati fọwọsowọpọ pẹlu wọn.
Sokoti Alagbede Ọrun jẹ ọkan gboogi lara awọn oṣere tiata Yoruba ti orukọ wọn milẹ titi ni Naijiria ati loke okun.
O bẹrẹ iṣe ere ṣiṣe lẹyin to kuro ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ, o si ti kopa ninu ere ti ko din marundinlọgbọn lati ọdun to ti bẹrẹ iṣẹ naa.


















