Mínísítà: Sísan owó iléẹ̀kọ́ ní fásitì àpapọ̀ yóò dópin

Awọn akẹkọọ jade ni fasiti

Oríṣun àwòrán, @Unibadan

Àkọlé àwòrán, O lodi ṣ'ofin fun awọn yunifasiti to jẹ ti ijọba apapọ, lati maa gba owo ileewe lọwọ awọn akẹ́ẹ̀kọ.

Ijọba apapọ ti sọ pe, o lodi ṣ'ofin fun awọn yunifasiti to jẹ ti ijọba apapọ, lati maa gba owo ileewe lọwọ awọn akẹ́ẹ̀kọ.

Minisita keji fun eto ẹkọ, Anthony Anwuka lo sọrọ naa l'Abuja lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ ijọba to waye l'ọjọru.

Igbakeji Aarẹ orilẹede Naijiria Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo lo dari Ipade naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Minisita sọ pe ijọba yoo ṣe iwadi lori ọrọ naa, yoo si f'opin si sisan owo ile iwe ni awọn awọn yunifasiti to jẹ t'ijọba apapọ.

Abawọle fasiti Maiduguri

Oríṣun àwòrán, STEFAN HEUNIS

Àkọlé àwòrán, Ijọba sọ fun ajọ to n ri si eto ekọ yunifasiti ni Naijiria NUC lati ṣiṣẹ lori ọrọ naa

O fi kun ọrọ rẹ pe, ijọba ti sọ fun ajọ to n ri si eto ekọ yunifasiti ni Naijiria NUC, lati ṣiṣẹ lori ọrọ naa, ki o si mu abọ wa.