Kampala blasts: Àdó olóró agbésùnmọ̀mí ṣekúpa èèyàn mẹ́ta ní Kampala

Awọn oṣiṣẹ n pana nibi ikọlu naa

Awọn agbesunmọmi ti kọlu ilu Kampala ti ṣe olu ilu Uganda nibi ti wọn ti ṣekúpa eeyan mẹta ti awọn to le l'ọgbọn si fi ara pa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn agbesunmọmi mẹta naa yin ado oloro ti wọn so mọ ara wọn l'ẹgbẹẹ gbọngan ile aṣofin ni Kampala.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn to ku nibi iṣẹlẹ ọhun si maa pọ sii nitori ẹya ara awọn si wa nilẹ ti ado oloro ṣe baṣu baṣu.

Ijọba ti di ẹbi iṣẹlẹ naa ru ẹgbẹ kan to n jẹ Allied Democratic Forces (ADF) to wa orile-ede DR Congo.

Ikọlu naa waye laarin iṣẹju mẹta pere.

ni arin gbungbun Kampala ni ibugbamu naa ti waye.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ẹwẹ, wọn tun ti ri ado oloro l'awọn ibikan niluu Kampala.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Fred Enanga, ẹru si n ba awọn eeyan titi di akoko yii.

Enanga ni ileeṣẹ ọlọpaa gbagbọ pe awọn agbesunmọmi si wa ni ilu Kampala.

O ni ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti ba agbesunmọmi kẹrin ti oun naa fẹ yin ado oloro.

Ọlọpaa meji lo wa ninu awọn tó bá iṣẹlẹ naa lọ nigba ti marun un ninu to fara pa wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.