Lekki EndSARS Report: Ọgá àgbà iléeṣẹ́ ológun Nàìjíría bẹnu atẹ́ lu bí wọn ṣé gbé èsì ìwádìí Endsars jáde

Lucky Irabor

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọga agba ileeṣẹ ọmọ ologun lorileede Naijiria,Ọgagun Lucky Irabor ti fesi lori ọrọ abajade igbimọ iwadii ENDSARS ti awọn kan ti lu sita.

O ni ilana ti wọn gba lati fi gbe esi yi jade ko boju mu ati pe ohun ko le ti sọrọ lori abajade yi nitori ijọba ko ti gbe jade sita.

Iwe abajade yi tawọn kan lu sita sori ayelujara sọ pe awọn ọmọ ogun Naijiria ṣeku pa awọn oluwọde lai nidi ni Lekki Toll Gate.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ìjọba Buhari ló ní ẹ̀bi, ẹ yé dá ẹ̀bi rú àwọn tó ń bèrè fún 'Yoruba Nation'

Lucky Irabor to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin to ṣabẹwo si Gomina ipinlẹ Edo ni ilu Benin ni ''bi abajade yi jẹ ootọ bi ko jẹ, mi o le sọ''

''Mo mọ pe ilana to y ni pe ki wọn fi abajade yi sọwọ sawọn alaṣẹ ki wọsi gbe iwe mii jade lori rẹ ki a to wa le sọrọ nipa abajade yi''

O ni ''amọ ṣa mo fẹ fi to yin leti pe ileeṣẹ ọmọ ologun Naijiria jẹ ileeṣẹ akọṣẹmọṣẹ. A ko si ro pe o yẹ kawọn eeyan maa bẹnu atẹ lu ileeṣẹ ologun bayi''

Ẹwẹ ajọ ajafẹtọmniyan Amnesty International ti kesi ijọba Naijiria lati ri pe awọn to lọwọ ninu ipaniyan Lekki Toll Gate foju wina ofin.

Wọn fi ọrọ yi sita ninu atjadekan loju opo Facebook wọn ni idahun si abajade igbimọ iwadii lori ikọlu to waye ni Lekki logunjọ oṣu Kẹwa ọdun 2020.

Amnesty sọ pe awọn dunnu si abajade yi ti o ṣafihan ootọ nipa nkan to ṣẹlẹ ni Lekki ni itako ohun ti ijọba Naijiria sọ pe o ṣẹlẹ.

Titi di asiko taa n ṣe akojọpọ iroyin yi, ijọba apapọ Naijiria ko ti fesi si ọrọ yi.