Bandit killing in Sokoto: Àwọn agbébọn dáná sun èrò ọkọ̀ 42 láàyè ní ìpínlẹ̀ Sokoto

yan bindiga

Oríṣun àwòrán, AFP

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria sọ pe ko din ni arinrinajo mọkanlelogun to jona ku lasiko ti awọn agbebọn dena de ọkọ wọn nipinlẹ Sokoto.

Awọn ọmọ wẹwẹ naa wa lara awọn to ku.

Lasiko ti awọn eniyan naa n rinrinajo lati ilu Sabon Birni lọ si ilu Isa nitosi ibode orilẹ-ede Niger ni iṣẹlẹ naa waye.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Sanusi Abubakar sọ fun BBC pe ọpọlọpọ eeyan lo tun ṣi n gba itọju nileewosan nitori ina to jo wọn.

Àkọlé fídíò, Murphy Afolabi: Kò dùn mí tí wọn bá ṣe yẹ̀yẹ́ mi torí mò fi sí pe ṣí, èdè Osogbo ìlú mi ni

Lara awọn to doola awọn to farapa sọ pe pupọ ninu awọn to ku lo jona kọja nkan ti eeyan le damọ.

Alẹ ọjọ Aje ni iṣẹlẹ naa waye, ṣugbọn iroyin rẹ ko tete jade sita nitori bi eto ibaraẹnisọrọ ko ṣe dara nibẹ.

Botilẹ jẹ pe ko ti i si ẹni to mọ koko bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye, iroyin kan sọ pe awọn agbebọn naa mọọmọ dana sun ọkọ akero naa pẹlu ero ninu rẹ, ti awọn miran tun ni ibọn ti awsn agbebọn yin mọ ọkọ naa lo mu ko gbina.

Àkọlé fídíò, Mama Deeper Life Ondo

Ni kete ti ọkọ naa gbina ni awọn agbebọn yii salọ lai mu ẹnikẹni.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ti bẹrẹ lori nkan to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Ṣé lọ́òtọ́ ọkọ àti ìyàwọ́ ní Mr & Mrs Kogberegbe? Àṣírí bí a ṣe ń ṣe ètò yìí rèé...

Iru iṣẹlẹ bayii, pe ki awọn agbebọn dana sun awọn ero ọkọ laaye ko waye ri ni agbegbe naa.

Àkọlé fídíò, Àwọn òṣìṣẹ́ Adedoyin jẹ́wọ́ fún wa pé àwọn pa àbúrò mi, ọ̀gá Adedoyin sì mọ̀ síi - Ẹ̀gbọ́n Timothy Adegoke