Sotitobire: Wolii Babatunde Alfa jáde lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

"Lati inu isin ọjọ isinmi ni mo gba de ọgba ẹwọn"
"Mo ke pe Ọlọrun, o si yọ mi'"
Ọrọ idunnu ti wolii Babatunde Alfa fi si ẹnu pẹlu ayọ ati idunnu niyi lasiko ti wọn ti tuu silẹ lọgba ẹwọn olokuta nipinlẹ Ondo.
- Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ondo sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ tó dá Sotitobire láre pé kò jí ọmọ kankan gbé
- Wọ́n bá òkú ọmọ ọdún méje tó di àwátì nínú 'cooler' nílé 'pásítọ̀' ní Ado-Ekiti
- Ìgbésẹ̀ láti dínà arìnrìnàjò ọmọ Nàìjíríà sí UK yóò da ètò rú fáwọn tó fẹ́ bá ẹbí wọn ṣe Kérésìmesì ní UK
- Mẹ́ta lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College tí Sylvester dárúkọ ti wà ní àkàtà ọlọ́pàá - Kọmisanna ọlọpaa Eko
Ni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹta oṣu kini ọdun 2021 ni ile ẹjọ kotẹmilọrun da Woli Babatunde Alfa ti ọpọ mọ si Sọtitobirẹ lare pe ko jẹbi ẹsin ijinigbe ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ondo fi ran an lọ si ẹwọn gbere lori ọmọdekunrin Gold to sọnu lasiko isin ọjọ isinmi ni ile ijọsin rẹ.
Iyawo rẹ, Busọla atawọn ọpọ ọmọ ijọ ni wọn lọ gbe wolii Sọtitobirẹ wale lati ọgba ẹwọn loni.









