Kí ló máa ń fa ìyípadà lára obìnrin lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe nǹkan oṣù?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
“Ní ọjọ́ àkọ́kọ́ tí mo bá ti rí nǹkan oṣù mi, níṣe ni inú mi máa bẹ̀rẹ̀ sí ní bàjẹ́, mo máa ń kórira gbogbo nǹkan tó máa ń dùn mí nínú, inú mi kàn máa ń bàjẹ́ sí gbogbo nǹkan.”
Ọmọ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n ni Fatima àmọ́ tó ń sọ nǹkan tí ojú rẹ̀ máa ń rí àti ìrírí rẹ̀ nígbà tó bá ti rí nǹkan oṣù rẹ̀.
Fatima, ẹni tó ti wà nílé ọkọ, ní gbogbo ìgbà tí òun bá ti rí nǹkan oṣù òun ni òun máa ń ṣe àkíyèsí àwọn àyípadà ní ara òun, tí ìwà òun náà yóò sì tún yípadà.
Ó ní “mi ò kìí lè jẹun ní ọjọ́ méjì àkọ́kọ́ tí mo bá bẹ̀rẹ̀ nǹkan oṣù mi àmọ́ àwọn ìpápátè bíi súùtì ló máa ń wù mí jẹ.
“Ọjọ́ mẹ́jọ ni mo máa fi ń ṣe nǹkan oṣù, tó bá sì máa fi di ọjọ́ kẹrin, gbogbo nǹkan tó máa ń ṣe mi máa ti lọ.”
Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ló máa ń dojúkọ irú àwọn nǹkan tí Fatima ń kojú yìí àmọ́ àwọn mìíràn kò ti ẹ̀ mọ nǹkan tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ rárá.
Bíi àpẹẹrẹ, Maryam Dauda, ẹni ọdún mọ́kàndínlógún tí kò ì tíì lọ́kọ ní ara kìí kan òun rárá àyàfi ìsàlẹ̀ inú tó máa ń kan òun àti pé òun máa ń jẹun lọ́pọ̀lọpọ̀.
Dókítà Kabiru Dara tó jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀yà ara obìnrin ní ilé ìwòsàn aládàni kan ní ìpínlẹ̀ Katsina ní àwọn obìnrin kan máa ń rí àyípadà ní ara wọn lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe nǹkan oṣù wọn lọ́wọ́.
Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin ló máa ń rí àwọn àyípadà yìí tó sì máa ń yàtọ̀ síra wọn.
Ó ṣàlàyé pé àwọn obìnrin kan máa ń kanra lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe nǹkan oṣù wọn lọ́wọ́, tí àwọn mìíràn sì kàn máa dákẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Dókítà Dara ní àwọn àyípadà yìí máa ń fa ìpèníjà láàárín lọ́kọláya tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ ara wọn nígbà tí ọkọ kò bá ní ìmọ̀ pípé nípa àwọn nǹkan yìí.
Ìpèníjà fún àwọn ọkùnrin
Ismail Lawal jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin tí ìyàwó rẹ̀ máa ń ní ìpèníjà lásìkò tó bá ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.
Lawal ní gbogbo nǹkan ló máa ń bí ìyàwó òun nínú láìsí nǹkan tó ń bi nínú pàtó tó lásìkò tó bá ti bẹ̀rẹ̀ nǹkan oṣù rẹ̀.
Ó ní ara ìyàwó òun kìí balẹ̀ rárá, tó sì jẹ́ pé tó bá sọ̀rọ̀ báyìí, nǹkan tó máa jáde lẹ́nu rẹ̀ kò ní dára lára àti pé tó bá ti ku ọjọ́ méjì sí ọjọ́ kan tí yóò bá ri nǹkan oṣù rẹ̀ ló máa ń bẹ̀rẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé àwọn máa ń jà gidigidi nígbà tí àwọn kọ́kọ́ fẹ́ra àwọn nítorí ó máa ń ya òun lẹ́nu bí ìwà rẹ̀ yóò ṣe kàn dédé yípadà lásìkò tó bá bẹ̀rẹ̀ nǹkan oṣù.
“Nígbà tí mo mọ nǹkan tó máa ń mu kanra, mo gbìyànjú láti dènà láti máa ba ní gbólóhùn asọ̀, tí mo sì máa ń ràn án lọ́wọ́ lórí àwọn iṣẹ́ ilé.”
Gẹ́gẹ́ bí Lawal, Fatima ní ọkọ òun náà máa ń ran òun lọ́wọ́, tó sì mọ̀ nípa nǹkan tó máa ń ṣe òun.
Kí ló máa ń fà á tí àwọn obìnrin fi máa ń rí àyípadà lára wọn lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe nǹkan oṣù?
Dókítà Kabiru Dara ní kìí ṣe àsìkò tí obìnrin bá ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́ nìkan ni wọ́n máa ń àyípadà lára wọn, ó ní tó bá ti ku bí ọ̀sẹ̀ kan sí méjì tí wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ nǹkan oṣù ni àyípadà náà ti máa ń fojú hàn díẹ̀díẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé àwọn àyípadà tó máa ń wáyé sí ẹ̀yà ara tí àwọn òyìnbó ń pè ní hòmóònù ló máa ń fà á.
Ó ní ọ̀nà méjì ni àsìkò ṣíṣe nǹkan oṣù obìnrin pín sí: ọjọ́ àkọ́kọ́ tó bá bẹ̀rẹ̀ nǹkan oṣù sí ọjọ́ kẹrìnlá, tí àsìkò kejì sì jẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá sí ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n tí nǹkan oṣù mìíràn yóò bẹ̀rẹ̀.
Ó ní àsìkò kejì yìí ni ọ̀pọ̀ obìnrin máa ń kanra, tí àwọn mìíràn sì máa ń wà nínú ìrònú.
“Lọ́pọ̀ ìgbà, kò ní sí nǹkan tó wu obìnrin lásìkò yìí, tí nǹkankan kò sì ní wù wọ́n ṣe, kòdá ọ̀pọ̀ nínú wọn ló kàn máa ń sunkún láì nídìí lásìkò yìí.”
Dókítà Dara ní nǹkan tó ń jẹ́ “Progesterone” ló máa ń fa àwọn àyípadà yìí fún àwọn obìnrin.
Bákan náà ló fi kun pé yàtọ̀ sí èyí, àwọn nǹkan mìíràn bíi àìsí olùrànlọ́wọ́ fún obìnrin, wàhálà àpọ̀jù máa ń fa àyípadà fún obìnrin lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe nǹkan oṣù wọn lọ́wọ́.
Ṣé gbogbo obìnrin ló máa ń rí àwọn àyípadà yìí?
Dókítà ní kìí ṣe gbogbo obìnrin ló máa ń rí àwọn àyípadà yìí tàbí ní ìpèníjà kankan lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.
Ó ní àwọn obìnrin kan ti gba kádàrá nípa àwọn àyípadà yìí tó ti di bárakú fún wọn débi wí pé ẹnikẹ́ni kò ní mọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ní àwọn ìpèníjà yìí.
Ó fi kun pé àwọn obìnrin mìíràn ní olùrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ọkọ àtàwọn ẹbí wọn tí kìí jẹ́ kí wàhálà pọ̀ fún wọn.
Ó sọ síwájú pé ó máa ń nira fún àwọn mìíràn débi wí pé wọ́n máa ń wà nílé ìwòsàn títí tí wọ́n máa fi parí nǹkan oṣù wọn.
“A ti ṣe àwárí rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ló máa ń fa àyípadà fún àwọn obìnrin lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe nǹkan oṣù wọn lọ́wọ́ tó fi mọ́ oúnjẹ jíjẹ.
“Awọn kan máa ń wá nǹkan dúndùn, tí àwọn mìíràn sì máa ń fẹ́ nǹkan tó bá ní iyọ̀ púpọ̀.”
Irú ìrànlọ́wọ́ wo ni àwọn obìnrin nílò lásìkò yìí?
Dókítà Kabir ní ìrànlọ́wọ́ tó péye ni àwọn obìnrin nílò látọwọ́ ọkọ àti àwọn ẹbí wọn tó bá wà ní àyíká wọn lásìkò yìí.
Ó ní gbogbo àwọn nǹkan tó bá lè fa ìpalára fún obìnrin lásìkò nǹkan oṣù bíi ṣúgà, iyọ̀, sígà fífà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lọ yẹ kí wọ́n jìnà sí.
Bákan náà ni àwọn obìnrin nílò láti jáwọ́ nínú jíjẹ àwọn nǹkan tó bá dùn jù nítorí òhun náà máa ń dákún àwọn ìpèníjà yìí.
Ṣé ààrùn ní àwọn nǹkan tó máa ń ṣe obìnrin lásìkò nǹkan oṣù?
Dókítà náà ní àwọn nǹkan tó máa ń ṣe àwọn obìnrin lásìkò tí wọ́n bá ń ṣe nǹkan oṣù wọn lọ́wọ́ kìí ṣe ààrùn tí kò bá ti pọ̀jù.
Ó ní ó dára kí àwọn obìnrin tó máa ń ní àwọn ìpèníjà yìí láti máa yọjú sí àwọn dókítà wọn tó bá ti ku bí ọjọ́ méjì sí mẹ́ta tí wọ́n máa ṣe nǹkan oṣù kí wọ́n lè gba ìtọ́jú tó péye.
Ó ní àwọn nǹkan yìí lè fà kí orí máa fọ obìnrin, inú rírun, àyípadà ohùn, jíjẹ oúnjẹ àjẹjù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.















