Wo ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tí kò lo omi rárá, ike àti gíláàsì tí wọn kò lò mọ́ ni wọ́n fi ṣe é

Ile igbọnsẹ kan ree ti ko lo omi rara eleyii tawọn ọdọ kan ladugbo ko ara wọn jọ ṣe.
Ile igbọnsẹ ọhun kii tilẹ run bii ile igbọnsẹ rara.
Awọn ọrẹ kan ni Kisumu ni orilẹede Kenya ni wọn kọ ile igbọnsẹ yii nitori wọn dagba ni awujọ ti ko si imọtoto.
Ọkan lara wọn, Vera Odhiambo Ouku ni ‘’a fẹ sẹ nnkan to maa tọjọ, ti a maa le tẹsiwaju pẹlu ẹ.
Ile igbọnsẹ ti owo rẹ ko ni gunpa ati eyi to maa pese iṣẹ fawọn ọdọ.
Ohun to ṣẹlẹ ni pe a o niṣẹ lọwọ, a wa wo o pe bawo ni a ṣe le koju ipenija yii ti yoo si tun pese iṣẹ fun awa naa.
Ti eniyan ba ti wọnu ile igbọnsẹ lati ṣe igbọnsẹ, ẹrọ to maa n gbe itọ to wa ni bii ọwọ iwaju ile igbọnsẹ yii maa gbẹ itọ yii.
Lẹyin naa ni awọn igbọnsẹ naa maa lọ si aaye kan nibi ẹyin ile igbọnsẹ yii.
Aaye ti igbẹ n lọ yii ni a ti fi awọn ọmọ kokoro kan to n jẹ black soldier fly si.
Kokoro black soldier fly jẹ kokoro ti kii panilara ti awọn ẹyin rẹ le ṣe ayipada awọn idọti si ohun tuntun.''
Awọn ike ati gilaasi ti wọn ko lo mọ ni wọn fi kọ ile igbọnsẹ yii.






