Saheed Osupa kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìjìnlẹ̀ ní fásitì Ibadan lẹ́ni ọdún 52

Saheed Oṣupa n gbọwọ Giwa fasiti Ibadan

Oríṣun àwòrán, instagram/kingsaheedosupa

Gbajugbaja akọrin Fuji, Akorede Babatunde Okunọla ti ọpọ mọ si Saheed Oṣupa wa lara awọn to kẹkọọgboye ni fasiti Ibadan, UI lọjọru.

Saheed Oṣupa kẹkọgboye ijinlẹ imọ nipa ọrọ oṣelu Bsc Political Science o si wa lara awọn akẹkọjade fasiti naa ti wọn gbe ọwọ oye le lori nibi ayẹyẹ ikẹkọgboye ile ẹkọ naa to waye lọgba fasiti Ibadan.

Gbajumọ akọrin naa bọ si oju opo Instagram rẹ lati fọnrere rẹ fun gbogbo agbaye pe oun ti dibaba oloye tuntun lẹka eto ẹkọ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ṣe igba akọkọ Saheed Osupa nile ẹkọ niyi?

Saheed Osupa atawọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ n ya fọto pọ

Oríṣun àwòrán, instagram/kingsaheedosupa

Saheed Oṣupa to jẹ ẹni ọdunmejilelaadọta ṣalaye ninu atẹjade to fi si oju opo ayelujara rẹ naa pe ipele oṣuwọn ijafafa imọ ẹkọ keji ti oyinbo n pe ni Second Class Upper ni oun gbe jade ni ile ẹkọ naa.

Ọdun 1987 ni Saheed Oṣupa jade ile ẹkọ girama ki o to tẹ siwaju lọ si ile ẹkọ gbogboniṣe Polytechnic Ibadan lati gba iwe ẹri Ordinary National Diploma ninu ẹkọ imọ nipa akoso okoowo (Business Administration lọdun 1992.

Saheed Osupa n darapọ mọ awọn agbagba oṣere ti wọn ti pada lọ kẹkọgboye lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti fi adagba ẹkọ ti.