Èèyàn 37 tẹra wọn pa níbi ìgbanisíṣẹ́ Iléeṣẹ́ ológun

Aworan asọ ileeṣẹ ologun

Oríṣun àwòrán, AFP

Ijọba ti kede pe o to eeyan mẹtadinlogoji to ti jade laye lẹyin ti wọn tẹ ara wọn pa lasiko eto igbanisisẹ ileeṣẹ ologun to waye ni paapa iseere kan to wa ni Congo-Brazzzaville.

Awọn eeyan yii lo n gbiyanju lati fi tipa tipa wọle si papa isere naa to wa ni olu ilu orilẹede naa, Brazzaville, eyi to fa itẹnipa gẹgẹ bi awọn araalu se sọ.

Lọsẹ to kọja ni ileeṣẹ ologun kede pe oun fẹ gba eeyan to le ni ẹgbẹrun kan sisẹ, bẹrẹ lati ọmọ ọdun mejidinlogun si ẹni ọdun mẹdọgbọn.

Ọpọ eeyan lo farapa ni alẹ lọjọ Aje ti isẹlẹ naa waye gẹgẹ bi ijọba ṣe sọ.

Ijọba ko darukọ iye eeyan to farapa sugbọn o kede pe awọn ti gbe igbimọ kalẹ labẹ asẹ olootu ijọba, Anatole Collinet Makosso.

Ọga ile igbokusi kan, Adelard Yvon Bonda sọ pe eeyan mejilelọgbọn ni wọn gbe oku wọn fun awọn mọlẹbi wọn

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Associated Press ṣe sọ ẹẹdẹgbẹrin eeyan lo n forukọ silẹ lojumọ fun igbanisisẹ naa lati ọsẹ to kọja ti ikede naa ti waye.

Airisẹse awọn ọdọ lo jẹ ida mejilelogoji ni Congo-Brazzaville, ti ọpọ wọn si ri ileeṣẹ ologun gẹgẹ bi ẹka kan lati ri isẹ.

Ileeṣẹ ologun ni awọn ti da igbanisisẹ naa duro bayii lẹyin ti isẹlẹ itẹnipa waye ni paapa isere Micheal d’Ornano ni dede ago mẹwaa alẹ.

Agbẹjọro ilu, Oko Ngakala ni iwadi yoo si bẹrẹ lori ohun to sokunfa itẹniyanpa naa.

Ogunlọgọ awọn ọdọ lo pejọ niwaju paapa isere naa lọjọ Aje.

Brandon Tsetou, akẹkọọ gboye to wa lara awọn ti ori yọ, ni oun ti to lati owurọ ọjọ naa.

"Gẹgẹ bi awọn to gbe eto silẹ se sọ, nitori o jẹ ọjọ to gbẹyin fun iforukọ silẹ ni ọpọ wa fi duro de alẹ pẹlu igbagbọ lati fi orukọ silẹ.

“Awọn eeyan kan ko farabalẹ to fi jẹ pe wọn fẹ fi tipatipa wọle sinu paapa isere naa, eyi to fa itẹniyanpa to waye, ti ọpọ eeyan si farapa, ti awọn mii gbẹmi mi.”

Ọga ile igbokusi, Adelard Yvon Bonda sọ fun AFP pe eeyan mejilelọgbọn ni wọn ti gbe oku wọn fun awọn mọlẹbi wọn.

“A ni lati kọkọ ṣe idaro awọn eeyan wa to jade laye. Eyi waye nitori ọpọ awọn ọdọ nilo isẹ.”