Kókó mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ nípa àìsàn Sémìí-sémìí (Asthma) réè

Ẹni to ni Asthma

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Gẹgẹ bi ajọ WHO ati Global Asthma Network ti ṣe sọ, o to eeyan miliọnu 334 ti aisan semisemi Asthma n ba finra lagbaye.

Nilẹ Africa, iye awọn to ko aisan yii wa laarin ida meji si ida mejilelogun ninu ida ọgọrun.

A ba dokita Ali Baddredine to jẹ onimọ nipa aisan naa, to n daamu ẹdọ fooro sọrọ.

Ilu Dakar lo wa ni Senegal.

Alaye ree to ṣe nipa awọn ohun to n ṣokunfa aisan Asthma, apẹrẹ rẹ ati awọn ọna ti ẹni to ba ni aisan yii le e fi gbe igbe aye alaafia.

Ki lo n jẹ Asthma?

Asthma jẹ aisan lile to maa n sakoba fun mimi nipa ki eeyan ma le mi daada tabi ko maa se eemi.

Ko gboogun ṣugbọn eeyan le ṣe itọju rẹ.

Gẹgẹ bi alaye ti Dokita Ali ṣe, ''apa isalẹ, ni aaye ti eeyan ti n mi ni asthma maa n daamu lara eeyan''

O le foju han nipa ikọ ẹgbẹ tabi ki oluwarẹ si maa le mi daada.

Ẹdọ fooro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki ni awọn apẹrẹ asthma?

Asthma a maa ṣe akoba fun ẹdọ fooro.

Apẹrẹ rẹ le foju han nipa ikọ, sisẹmi,nini inira lati mi llẹyin ti eeyan ba ṣe iṣẹ wahala diẹ.

Onimọ salaye pe awọn apẹrẹ yi a maa yatọ lati eeyan kan si omiran to si ni ṣe pẹlu asiko ninu ọjọ.

''Asthma maa n saba daamu eeyan lalẹ tabi lowurọ kutu'' gẹgẹ bi Dokita Ali Baddredine ti ṣe sọ.

Ki lo n se okunfa aisan Asthma ati awọn nnkan to maa n da kun aisan yii lara?

Ọpọ nkan lo maa n da kun aisan yi lara tabi to le ṣokunfa rẹ.

Akọkọ ni adamọ onitọun ati awọn nkan mii to wa layika rẹ to le dakun aisan yi tabi ko mu ko de si ara eeyan.

Bi eeyan ba n fa eefin simu eleyi le sokunfa idaamu fun ẹni to ni asthma lara.

Awọn eefin kan lewu ni paapa gẹgẹ bi ti siga to ni taba ninu to le dakun inira fun aaye ti onitọhun fi n mi to si le ṣakoba alaafia rẹ.

Bi eeyan ba wa ni itosi awọn eruku, idọti, irun ẹranko, oorun ọṣẹ́ ifọsọ ati awọn turari mii, wọn le mu ki asthma de si onitọun.

Dokita ṣalaye pe ẹlomiran naa le ni asthma gẹgẹ bi ohun taa bi mọ.

Ko si nkan ti ko le fa asthma tabi ko jẹ ki asthma yọju si ara eeyan gẹgẹ bi Dokita Badreddine ṣe sọ.

Baddredine

Oríṣun àwòrán, Dr. Ali Baddredine

Àkọlé àwòrán, Dr. Ali Baddredine

Ki ni ibaṣepọ laarin iyipada oju ọjọ ati Asthma?

Awọn to ni asthma lara wa ninu ewu lọwọ iyipada oju ọjọ.

Idi ni pe o maa n lapa lori mimi wọn ti wọn a si maa koju oriṣi nkan to n fa inira fun mimi wọn.

Gẹgẹ bi awọn akọṣẹmọṣẹ ti ṣe wi,awọn afẹfẹ buruku lati ẹnu ọkọ taa n wa kaakiri, ile iṣẹ to wa layika ati afẹfẹ buruku mii taa n mi sinu le ṣakoba fun ẹni to ni asthma.

Dokita Badreddine kilọ pe 'Gbogbo awọn nkan wọnyi le maa mu ki oju ara ibi ti asthma sodo si maa pade inira ti eleyi si le mu ki ẹni ti asthma wa lara rẹ bẹrẹ si ni ri inira pẹlu mimi rẹ''

Awọn wo lo wa ninu ewu julọ?

Ko si ẹni ti asthma kii mu amọ awọn ti wọn ko dagba pupọ lo maa n han leemọ julọ.

Botilẹ jẹ wi pe a fidi rẹ mulẹ pe ọmọ le ko lara obi, kii ṣe gbogbo igba lo maa n ri bẹẹ.

Ko si akọsilẹ pe iru awọ́n eeyan kan lo le ko aisan asthma yi amọ o ṣeeṣe ki o farahan lara awọn eeyan kan ju awọn mii lọ.

Ninu wọn la ti ri awọn to wa lati idile ti aisan yi a maa mu wọn, awọn ti ifo a maa da laamu, awọn ọmọ ti ọjọ wọn ko pe ki wọn to bi wọn, awọn ọmọde ti wọn ni kokoro aifojuri to n koba ọna ọfun wọn nipa mimi daada.

Awọn mii ni awọn to sanra pupọ, awọn to maa n fa atẹgun idọti simu layika wọn ati awọn mii.

Gẹgẹ bi dokita Ali Baddredine ṣe wi,''a ko le sọ pato pe iru awọn eeyan kan ni aisan yi le da laamu''

O ni lootọ ni pe ti eeyan ba ni ọmọde ti kokoro aifojuri n fa ọfinkin tabi irufẹ aisan bẹẹ fun loore koore ti ko si jẹ ko ribimi daada, iru ọmọ naa le ni asthma lọjọ iwaju.

Ki ni iyatọ laarin asthma ati sinusitis?

Sinusitis jẹ nkan to maa n kọwọrin pẹlu asthma ṣugbọn yatọ si asthma to n ko inira ba ẹdọ fooro, iho to wa laarin inu imu ni Sinusitis maa n ba finra.

O maa n saba wa lara gbogbo awọn to ni ailera asthma.

Idi tawọn eeyan fi maa n da sinusitis papọ mọ asthma ni pe awọn to wa ninu ewu asthma maa n ko sinusitis tori bi apẹrẹ wọn ṣe papọ.

Onimọ yi sọ pe ''sinusitis jẹ ailera to maa n ba apa oke oju ọna ti atẹgun n gba wọ ọna ọfun wa.Sinuses naa fara pẹ nitori pe oju ọna toro imu naa ja si ti ọna ọfun.

Kii ṣe gbogbo asthma lo ni ohun ṣe pẹlu sinusitis amọ ti eeyan ba ti sinusitis o ni lati tete bẹrẹ itọju rẹ nitori o le rin lati oju iho imu lọ́ si isalẹ oju ọna ti eeyan n gba lati maa si sita.

Aworan afihan ọkan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bawo la ṣe n tọju Asthma?

O se pataki lati mọ pe itọju to daju lati koju asthma ni ki eeyan dena rẹ.

Eyi ni ṣe pẹlu idanilẹkọ awọn alaisan.

Lati le kọdi ikọlu asthma, awọn to ni asian yi lara gbọdọ yago fun siga fifa,tabi ki wọn wa ni ibi ti eefin pọ si ki wọn ma ba wa ni inu ewu ikọlu asthma.

Wọn tun gbọdọ yago fun awọn nkan elo to le mu ki oju ọna fun maa rin onitọun bi ọda, gọọmu ti wọn fi n lẹ nkan ati awọn nkan elo inu ile mii.

Ninu gbogbo alaye yi, idanilẹkọ ṣe pataki ni paapa bi wọn ko ṣe ni dakun ewu lasiko ti ikọlu asthma ba de ba alaisan.

Ọmọkunrin to ni asthma to n lo inhaler

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Se awọn to ni Asthma le ṣe ere idaraya?

elere idaraya to n fa inhaler simu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ohun to se anfaani fun ni to ba ni aisan Asthma

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ṣeeṣe ki a seto idaraya fun ẹni to laarẹ lara.

Ere idaraya naa a maa mu ki awọn iṣan ara wa ni ipo to peye ti yoo si mu adinku ba ijaiya ọkan.

Dokita Baddredine sọ pe ''idaraya jẹ oju pọnna itọju alaisan.Pupọ awọn elere idaraya ti wọn kajuẹ lo ni asthma.Ohun to ṣe pataki ni ki wọn tọju asthma yi daada.Koda awọn oogun asthma kan wa ti ko tako ofin ogun lilọ awọn elere idaraya''

O fi kun pe ''wiwẹ ninu omi, kẹkẹ gigun, rinrin lọna ti ko ni pa ni lara wa lara awọn ohun to ṣe anfaani fun ẹni to ni asthma.''

O ni ere sisa ni paapa lọna jinjin lasiko otutu le mu ki asthma kọlu ẹni to ni lara tẹlẹ.Lati le dena eyi, ẹni to ni asthma lara ni lati lo irinṣẹ kan ti wọn maa n fa simu taa mọ si bronchodilator ni nkan bi iṣẹju mẹẹdogun ṣaaju ki wn to bẹrẹ si ni sare.

Mimọ ọjọ ori ati iru ẹni taa n sọrọ nipa rẹ yi ṣe pataki ki wọn to le kopa ninu eyikeyi ere idaraya.

Awọn to ba ni asthma lara gbọdọ kan si onimọ ilera ki wọn to kopa ninu ere idaraya kankan.

Asthma a maa pa eeyan bi??

Obinrin to n fa inhaler simu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lootọ ni asthma ma buru amọ ikọlu asthma le mu ẹmi eeyan lọ.

Ni paapa to ba jẹ asthma to lagbara.Eyi taa n wi yi jẹ ikọlu asthma to ṣẹlẹ lojiji to si le ran ẹni naa si ile iwosan pajawiri.

O ni awọn eeyan kan ti wọn da itọju wọn duro lai ṣe pe dokita sọ bẹẹ fun wọn.

Asthma le jẹ aisan to buru ṣugbọn ta ba tọju rẹ bo ṣe yẹ ko ni sewu.

O fikun pe nigba mii aisan mi yoo mu ẹmi awọn eeyan lọ tawọn o si ni asthma lo pa tori bi awọn apẹrẹ wọn ṣe foju jọ ara wọn.

Bi eeyan ba tẹle amọran awn akọṣẹmọṣẹ oniṣegun, yoo gbe igbe aye alaafia koda ko ni asthma.

Dokita pẹlu alaisan

Oríṣun àwòrán, Getty Images