Okùnrin kan ra àpò ìrẹsì mẹjì, ó fi ọ̀dọ́kùnrin méjì ṣe onídùró nílùú Eko

Oríṣun àwòrán, Armiyau Shuaibu
Obinri kan ti wọnu oko gbese lẹyin ti okunrin kan ra irẹsi ninu ṣọọbu rẹ lai san owo fun, ṣugbọn to fi awọn ọmọkunrin meji silẹ ni ṣọọbu ọhun dipo owo.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, Ọjọbọ ni okunrin naa wọ inu ṣọọbu Olabisi Opeyemi to wa ladugbo Felicia Oke, lagbegbe Olowora niluu Eko.
Nibẹ lo si ti sọ pe oun fẹ ra apo irẹsi meji, toun ti awọn ọdọkunrin meji ti iye ọjọ ori wọn ko ju ọdun marundinlogun lọ.
Aburo Opeyemi, Alima, to wa ninu ṣọọbu ọhun lasiko naa ta irẹsi fun okunrin naa pẹlu igbagbọ pe aburo rẹ ni awọn ọdọkunrin meji ọhun.
- Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ń se ọbẹ̀ tó máa ń fún wọn ní ìbejì ní Igbo-Ora
- Owó yíyá kò kọjá àfaradà tí a bá ti lò ó dáadáa- Aarẹ Buhari
- Òrùka ìgbéyàwó,ìlẹ̀kẹ̀ ìdí àti àwọn nkán míràn tàwọn eléwé ọmọ fí n ṣètò ìfètòsọ́mọbíbí
- Ta ni ilẹ̀ Yoruba yóò gbé ipò Ààrẹ fún nínú Tinubu, Osinbajo àti Fayemi lọ́dún 2023?
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba orílẹ̀-èdè Benin ti gba ibọ̀dè lórí ẹjọ́ Sunday Igboho?
- Mo dúpẹ́ pé Ọlọrun kò jẹ́ kí àwọn ọmọge tí mo kọ́kọ́ dẹnu ìfẹ́ kọ gbà láti fẹ́ mi - Mike Bamiloye
- Bí a kò bá yá owó, Nàìjíríà ò bá má bọ́ nínú ìfàsẹ́yìn ọ̀rọ̀ ajé - Mínísítà ètò ìsúná
- Chiwetalu Agu ti gba òmìnira lọ́wọ́ àwọn sọ́jà tó mú u
- Ojú wa rí tó lásìkò tì a wà ní àhámọ́ ajínigbé, koríko la jẹ fún ọjọ́ 52
Lẹyin ti okunrin naa ra apo irẹsi meji ọhun, o fi awọn ọdọkunrin meji naa silẹ si ṣọọbu naa, o si sọ fun Alima pe oun n bọ wa lati lọ gba owo nitosi.
Ṣugbọn lẹyin iṣẹju diẹ ti okunrin naa ko tete de ni ọkan lara awọn ọdọkunrin to fi silẹ sọ pe oun fẹ lọ ṣawari rẹ.
Ko pẹ si asiko naa ni ọdọkunrin keji naa tu sọ pe oun fẹ maa lọ ṣugbọn Alima kọ jalẹ pe ayafi ti okunrin to ko awọn mejeji wa ba pada wa, ṣugbọn ọdọkunrin naa ni oun ko mọ okunrin naa ri.
Ọdọkunrin ọhun sọ pe ni ṣe okunrin naa pade lẹba ọna to si bẹ oun lati ran an lọwọ lati gbe irẹsi ninu ṣọọbu Alima.
Asiko yii lo ti han gbangba si Alima pe onijibiti ni okunrin ọhun, ati pe o ti fẹsẹ fẹ.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, ẹgbọn Alima to ni ṣọọbu naa, Opeyemi sọ pe gbese nla ni iṣẹlẹ naa da si oun lọrun.
O ni oun ko fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti nitori ẹni mimọ ni ọkan lara awọn ọdọkunrin naa jẹ si oun ni adugbo
O ṣalaye pe "Mi o si ni ṣọọbu lasiko ti iṣẹlẹe naa waye nitori mo wa lori idubulẹ aisan, ṣugbọn lẹyin wakati diẹ ti okunrin naa ra ọja tan ni mo to mọ pe wọn ti lu aburo mi ni jibiti."
"Iṣẹlẹ naa da omi tutu si mi lọkan nitori gbese nla lo da silẹ fun mi."
Ẹwẹ, awọn eeyan kan ni adubo ti iṣẹlẹ naa ti waye ti sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ṣe ni okunrin to ra irẹsi ọhun fi oogun ba Alima sọrọ.
Titi di akoko ti an ko iroyin yii jọ, wọn ko tii foju ganni okunrin ọhun, ko si si ẹni to le sọ ibi to ti wa.
- Àjọ WHO gbé abẹ́rẹ́ àjẹsára àìsàn ibà jáde fún ilẹ̀ Afrika
- Wo kókó mẹ́ta nípa àbá ìsúná ₦16.39trn fún ọdún 2022 tí Buhari gbé lọ sílé aṣòfin
- Àwọn Òṣèré fíìmù Yorùbá tẹ́ ò ro tó tí jápaa lọ ìlú Òyìnbó rèé
- Ẹ wo Ajá tó ń gbọ́ òórùn àìsàn ibà, ẹja tí a kò gbọdọ̀ pa àti ọọ̀nì tó ń gbọ́ àdúrà ní Ìbàdàn
- Chiwetalu Agu ti gba òmìnira lọ́wọ́ àwọn sọ́jà tó mú u
- Àwọn olọ́kadà ti gba àwọn ìyàwó wa tán nítorí a kò lówó lọ́wọ́- Àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ni Benue
- Kí ló lè mú kí ará ìlú fárígá pátápátá nítorí pé kò sí iná mọ̀nàmọ̀nà?

















