Bola Tinubu padà dé sí Naijiria lẹ́yìn tó lọ gbàtọ́jú nílùú London

Tinubu returns to Nigeria

Oríṣun àwòrán, Jubril Aremu Gawat

Eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu ti pada si Naijiria lẹyin to lo ọpọ ọjọ nilẹ Gẹẹsi nibi to ti lo gba itọju.

Alẹ ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021 yii ni aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC balẹ si Naijiria lati ilu London.

Ninu atẹjade ti ọkan lara awọn agbẹnusọ gomina Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko, Jubril Aremu Gawat fi lede, o ni Tinubu pada wa si Naijiria lẹyin to lọ ṣiṣẹ abẹ orokun loke okun.

Gawat ni kii ṣe pe Tinubu lo ṣiṣẹ abẹ kan to lewu fun ẹmi rẹ, ṣugbọn ẹsẹ nikan lo n yọ ọ lẹnu, o si ti gbadun bayii.

O ni "O ti pari itọju orokun rẹ. o si ti gbadun. Ni bayii to ti pada de si Naijiria o ti ṣetan lati tẹsiwaju ninu akitiyan rẹ lati ri daju nnkan ṣenu ire fun gbogbo mutumuwa, ati ki Naijiria si le tẹsiwaju."

Tinubu returns to Nigeria

Oríṣun àwòrán, Jubril Aremu Gawat

Lẹyin naa lo ni Tinubu dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọmọ Naijiria fun adura ati aduroti wọn ni gbogbo asiko to fi lọ gba itọju loke okun.

Ti ẹ ko ba gbabe, ṣaaju ni awọn iroyin kan ti kọkọ gbode kan pe Bola Tinubu ti jade laye.

Ṣugbvọn agbẹnbusọ rẹ, Tunde Rahman sọ pe irọn nla ni iroyin naa ati pe ko ṣaisan kankan.

Àkọlé fídíò, Ṣé ìwọ mọ̀ pé Olodumare lè lo Aje láti gbé ẹ lọ síbi ire?- Abiodun Fatomilola

Lẹyin ọsẹ diẹ si asiko na ni gomina ipinlẹ Eko ṣabẹwo si, ti awọn oloṣelu mii ti iye wọn le ni ọgbọn si lọ ṣabẹwo si niluu London pẹlu.

Ẹwẹ, bo tilẹ jẹ pe Tinubu ko tii sọ ni gbangba pe oun yoo dije du ipo Aarẹ lọdun 2023, awọn ẹmẹwaa rẹ ti bẹrẹ si n ṣe ipologo ibo Aarẹ lẹyin rẹ.

Àkọlé fídíò, Ẹni tó bá ni kí n fi iṣẹ́ kòkò mímọ sílẹ̀, mi ò lè fẹ́ẹ láéláé - Adekemi Àgùnbánirọ̀

Ni iroyin miran, agbarijọpọ ẹgbẹ awọn gomina ni iha Guusu Naijiria ti fẹnuko pe iha Guusu Naijiria lo yẹ ki Aarẹ ti yoo gori alefa lẹyin Muhammadu Buhari ti wa, ṣugbọn awọn akẹgbẹ wọn lati iha Ariwa ti ni ko si ohun to jọ bẹẹ nitori ohun ti wọn n bere fun ko ba ofin mu.

Àkọlé fídíò, Nàìjíríà kàn wà ni, ẹ ò páàsì, ẹ ò féèlì, ẹ ò kúrò ní kíláàsì kan náà - Àwọn ọ̀dọ́

Lara awọn oloṣelu ti orukọ wọn ti n gbode pe ipo Aarẹ naa tọ si nilẹ Yoruba yatọ si Tinubu ni igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osibajo ati gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi.

Wayi o, ko ṣi ẹni to tii mọ ibi ti ọrọ naa yoo ja si niroti ẹnikẹni ninu awọn oloṣelu mẹta naa ko si sọrọ soke lori ipinnu wọn.

Àkọlé fídíò, Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu