Japan Princess Mako: Ọmọbabìnrin ní Japan ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú olólùfẹ́ rẹ̀ Kei

Princess Mako

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọmọbabinrin Ilẹ Japan, Princess Mako ti ṣe igbeyawo pẹlu ọkọ rẹ, Kei Komuro lẹyin ọdun mẹrin ti wọn ti wa lori rẹ.

Princess Mako to fẹ Kei Komuro to jẹ ọmọ atapatadide naa yoo padanu ipo rẹ gẹgẹ bi ọmọ ọba, eleyii ti kii ṣẹlẹ si awọn ọmọọbakunrin.

Bakan naa ni ko ni lee ṣe igbeyawo alariwo bii idile ọba ti maa n ṣe, ti ko si tun ni gba owo ti wọn ma n fun awọn ọmọ ọba to ba kuro ninu ẹbi.

Oun ni ọmọbabinrin akọkọ ti yoo kọkọ ṣe iru ipinnu yii.

Ọkọ ati iyawo ni afojusun awọn eniyan fihan pe wọn yoo pada si orileẹde Amerika nibi ti Komuro ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi agbẹjọro.

Eleyii ni awọn eniyan ri ti wọn fi n ṣe apejuwe laarin Ọmọọbakunrin Ilẹ Gẹẹsi, Harry ati iyawo rẹ, Meghan Markle ti wọn fi ipo wọn naa silẹ, ti wọn si kuro ni Ilẹ Gẹẹsi.

Bi Markle ṣe koju ipenija pẹlu awọn oniroyin ni Ilẹ Gẹẹsi, ni Komuro naa n koju ọpọlọpọ iṣoro pẹlu awọn oniroyin ati ariwisi lori bo se n da irun rẹ silẹ, ti wọn ni ko ba igbe aye ẹni to fẹ fẹ ọmọoba mu.

Lasiko ti ọmọbabinrin Mako naa n ba awọn oniroyin sọrọ ni ilẹ Japan, lo fi tọrọ aforiji lọwọ awọn araalu ti oun ba ṣẹ pẹlu igbeyawo oun.

Princess Mako

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Amọ, o ni ko si aniani, oun ko le e fi ololufẹ oun silẹ lae ati laelae.

Ọkọ naa ninu ọrọ tirẹ ni, ''mo fẹran Mako denu denu, aye kan si ni ani, nitori naa mo n gbiyanju lati lo pẹlu ololufẹ mi Mako.''

Àkọlé fídíò, Ooni: A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa

O fikun un pe ibanujẹ ọkan lo jẹ fun oun pẹlu bi awọn oniroyin ẹlẹjẹ ṣe da ọgbẹ ọkan si ara iyawo oun, eleyii to fi mu ki ara rẹ ma ya fun igba diẹ.

Ọdun 2017 ni wọn kede pe awọn fẹ ṣe igbeyawo, amọ wọn da duro lẹyin ti iroyin jade pe iya Komuro jẹ ọkọ afẹsọna rẹ tẹlẹri ni gbese ti ko san an pada.

Ile Ọba ni kii se idi ti awọn fi da igbeyawo naa duro niyẹn, amọ gbogbo gbese naa lo ti di sisan bayii.

Bakan naa ni awọn araalu koju oro si igbeyawo rẹ, ti wọn si ṣe ifẹhonuhan tako igbeyawo naa.

Oniroyin ileeṣẹ BBC lati ilẹ Japan, Rupert Wingfield-Hayes ni idi ti awọn eniyan fi n ṣe ifẹhonuhan ni pe wọn ko kaa si pe Komuro yẹ lẹni to lee fẹ ọmọọba awọn.

Wọn ni atapata dide ni Komuro, ti mọlẹbi rẹ ko si ni nkan pato to jẹ moriya fun awọn eniyan lati wo mọ ọ lara.

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi

Oniroyin BBC naa fikun pe igba akọkọ kọ ni yii ti ẹbi ile ọba naa yoo ni awọn idojukọ bi eleyii.

Iya-Iya Mako, Ọbabinrin Emerita Michiko ni ko lee sọrọ fun bi ogun ọdun lẹyin ti awọn oniroyin dunkoko mọ pe ko yẹ ni iyawo ọba.

Bakan naa ni iyawo ẹgbọn Mako, Ọbabinrin Masako naa ni idojuko nitori ko bi ọmọkunrin ti yoo gori itẹ baba rẹ.

O fikun un pe awọn ọmọbinrin lati idile ọba lorilẹede Japan ma n ni idojuko ti wọn ko ba tẹle alakalẹ ti awujọ fẹ lọwọ wọn.

Ero araalu ni pe awọn obinrin yii gbọdọ jẹ alatilẹyin ọkọ wọn, ki wọn bi ọmọkunrin, ki wọn si jẹ ẹni ti yoo ma gbe asa ati iṣe ilẹ Japan ga.

Àkọlé fídíò, 'Mi ò yàtọ sí Krìstẹni tàbí Mùsùlùmí tóun náà da ẹsìn rẹ pọ mọ jíjẹ Dokita, Babaláwo Dókítà l'èmi'