Nnamdi Kanu: Garba Shehu ní aráàlú kò ti IPOB lẹ́yìn, ariwo àti ẹ̀hónú ori ayélujára lásán ló ń ṣe

Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba onídúró rẹ̀ tí Nnamdi Kanu sá kúrò ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà

Ileesẹ aarẹ lorilẹede Naijiria ti kede pe bi wọn se n ba Nnamdi Kanu se ẹjọ, ẹni tii se asaaju ikọ to n pe fun idasilẹ orilẹede Biafra, IPOB, ni yoo fopin si igbesẹ ijijagbara ọhun.

Garba Shehu, agbẹnusọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari lo kede bẹẹ pẹlu afikun pe awọn eeyan ẹkun ila oorun Naijiria ko se atilẹyin fun iwa ijijagbara ti Kanu n hu.

Shehu ni awọn gomina ati awọn asofin lẹkun ila oorun Naijiria gan ko gba ti ẹgbẹ IPOB ati awọn igbesẹ fun iyapa Naijiria ti wọn n gbe.

Garba Shehu sisọ loju ọrọ yii nigba to n fesi si ariwisi ti iwe iroyin atigbadegba kan, The Economist, to wa nilu London sọ nipa Aarẹ Buhari.

Atẹjade kan ti Garba Shehu fi sita loju opo Facebook rẹ lo ti sọ pe ijọba apapọ ti n gbe igbesẹ to yẹ lati ri pe gbogbo agbaye mọ ikọ IPOB bii ẹgbẹ adunkookomọni.

"Ni ẹkun Ila oorun guusu Naijiria, ikọ IPOB, ti iwe iroyin The Economist, sapejuwe rẹ bii eyi ti ko mọ ohun to n se, ni opin ti n de ba pẹlu bi wọn se mu asaaju rẹ.

"Ijọba yii lo ti n fi aayan kun aayan rẹ lati ri daju pe awọn alatilẹyin wa nile ati lẹyin odi lẹ orukọ ẹgbẹ adunkookomọni mọ IPOB lara."

Àkọlé fídíò, Ooni: A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa

Shehu sọ pe igbesẹ yii yoo fi opin si awọn anfaani owo ilẹ okeere to n ri gba, ti yoo si fopin si ijijagbara rẹ.

O ni ariwo ati ẹhonu lasan ti ikọ IPOB n se lori ayelujara ko se afihan pe awọn araalu n ti lẹyin.

"Gbogbo awọn gomina ti wọn dibo yan, awọn oloselu atawọn asofin ipinlẹ lẹkun ila oorun guusu, nibi ti IPOB ni oun ti wa, lo ti kẹyin si patapata."