Zoning of Presidency: Ghali Na’Abba ní Buhari ń dá ìjọba ṣe láì fi lọ ẹnikẹ́ni

Oríṣun àwòrán, Presidency
Olori ile asoju sofin tẹlẹ, Ghali Umar Na'Abba ti salaye idi ti awọn eeyan ni ariwa Naijiria se n tako pinpin ipo aarẹ si ẹkun kan.
Na'Abba ẹni to salaye ọrọ yii lasiko ifọrọwerọ kan lori mohunmaworan Daily Trust ni awọn eeyan ẹkun ariwa lo ri saa isejọba aarẹ Buhari bii fifi anfaani ti ẹkun ariwa ni sofo danu.
O ni ọpọ eeyan Ariwa ni ko tako ki ipo aarẹ lọ si ẹkun miran ni asiko yii nitori pe wọn ko ri anfaani kankan lati ara isejọba Buhari.
- DSS 20, Sọ́jà 200 àti Babaláwo mẹ́ta ló kọlu ilé Sunday Igboho
- Liverpool faṣọ iyì ya mọ́ Man U lára, ó wọ Ole àti Ronaldo láṣọ ẹ̀tẹ́
- "Àwọn ọ̀dọ́ ti ṣetán láti dá wàhálà sílẹ̀ fún ìdáǹdé Sunday Igboho"
- Ẹ̀yin aráàlú, ẹ máse pa ara yín nítorí olóṣèlú kankan - Makinde
- Ǹjẹ́ òbìnrín tún le lóyún lásìkò tó wà nínú oyún, kíní sáyẹ́nsì sọ?
- Torí N200,000 ni mo ṣe lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ ajínigbé láti jí bàbá mi gbé - Afurasí
- Ẹ wo alágbe méje tó lówó jùlọ ní àgbáyé
- Wo ọmọ Nàíjíríà tó wà nínú Mùsùlùmí 500 tó lààmì laaka lágbàáyé
- "Gbàǹjo! Ta ni yóò rà mí ní ₦20m, mo wà fún títà"
- Nnkan ìtìjú gbàá ni bí wọ́n ṣe já ọgbà ẹ̀wọ̀n l'Oyo - Iba Gani Adams
"Kii kuku se pe awọn eeyan ẹkun guusu ati ariwa n kọju ogun si ara wọn amọ ko si bi eeyan yoo ti se ọrẹ to lai ni aawọ nigba mii. Awọn aawọ yii si lo waye nitori awọn idi kan."
Olori ile sofin tẹlẹ naa wa se apejuwe aarẹ Buhari bii ẹni to pin ẹkun guusu ati ariwa niya, ti wọn si ro pe o n se ojusaaju fun ẹkun kan.
Na'Abba ni se ni aarẹ n da sisẹ funra rẹ, ti ko si fi gba imọran amọ to n dari ilẹ yii ni ilana konko jabele, kaluku lo n se tiẹ.
"Ko seese ki eeyan kan maa dari orilẹede kan lọna tawọn eeyan yoo fi ro pe tinu ara rẹ lo n se, eyi ti ko kan araalu.
Amọ to ba jẹ pe awọn igbesẹ adanikan gbe yii kan awọn araalu ati eto idẹrun wọn, a jẹ pe o dara nigba naa.
Awọn eeyan ẹkun guusu lero pe aarẹ jẹ ẹlẹya mẹya, ti ko si le dari orilẹede yii.
Bẹẹ ni eeyan kan tiẹ sọ fun mi pe ọkunrin yii gan ko le dari ile rẹ gan, bawo wa ni yoo se dari orilẹede."
Na'Abba ni ko si bi wọn yoo se pin ipo aarẹ si ẹkun kan, ti yoo tẹ gbogbo eeyan lọrun
O ni lẹkun ariwa bayii, erongba gbigbe ipo aarẹ lọ si ẹkun miran ko jẹ itẹwọgba fun ọpọ eeyan.
Ero ọpọ eeyan ni pe akoko ti aarẹ yii lo lori oye lo jẹ adanu, ti wọn ko si ri anfaani kankan nibẹ.
"Ki wa lo de ti awọn eeyan kan yoo se maa sọrọ nipa pinpin ipo aarẹ? Niwọn igba ti wọn ba ti gbagbọ pe awọn ni iye eeyan to yẹ lati dibo yan aarẹ tuntun sipo.
Kii ba ẹnikẹni jiroro, niwọn igba to ti daba bẹẹ, o n da sisẹ fun ara rẹ ni.
Eeyan ko le jẹ aarẹ tabi wa ni ipokipo nitori pe oun nikan lo gbọn julọ nitori ko si ẹni to gbọ tan."














