Rumuekpe Port Harcout explosion: Èèyàn 25 jóná níbi ọ̀pá epo tó fọ́

Ọpa epo

Oríṣun àwòrán, Other

Ko din ni eeyan mẹẹdogun to jona kú nibi ibugbamu to waye ni ibudo ifọpo kan ti ijsba ko fọwọ si nipinlẹ Rivers.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle sọ pe awọn ọmọde wa lara awọn to ku.

Bakan naa n i awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ina bẹrẹ si ni jo lẹyin ri ọpa epo kan bu gbamu ni ibudo ifọpo ayederu naa to wa ni ilu Rumuekpe, nijọba ibilẹ Emohua, nipinlẹ Rivers.

Ibugbamu akọkọ yii lo tun ran awọn ọpa epo miran to wa ni agbegbe ọhun, ti gbogbo si gbina.

Ọpọlọpọ ile lo jona, ti awọn eeyan si farapa.

Nkan to wọpọ ni agbegbe Niger Delta ni ki awọn ọdọ ma a wa epo bẹtiro ni awọn ibudo ti ko ba ofin mu, nipa fifọ ọpa eporọbi.

Awọn alaṣẹ sọ pe o to ẹgbẹrun lọna ẹigba àgbá epo ni Naijiria n padanu lojoojumọ, nitori bi awọn kan ṣe n fọ ọpa epo.