Tunde Bakare: Gbogbo ìlérí ààbò tí Buhari ṣe ló kùnà

Tunde bakare

Oríṣun àwòrán, thetbakareiknow

Pasitọ agba fun ijọ Citadel Global Community, Tunde Bakare ti sọrọ nipa bi ẹya miran ni Naijiria yoo ṣe dipo aarẹ mu.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu iwe iroyin This Day, Bakare ni ẹnikẹni to ba n gbero lati di aarẹ Naijiria gbọdọ dunadura pẹlu awọn ara oke ọya.

O ni oun ko lero wi pe awọn eeyan apa ariwa Naijiria yoo finu fẹdọ gbe ijọba kalẹ fun ẹya miran.

O fi kun pe laisi iranwọ lati ọdọ awọn ẹya to kú, oun ko lero pe ẹkùn kankan ní Naijiria le da nikan gbe ararẹ de ipo aarẹ, nitori náà, ifọwọsowọpọ ati idunadura ṣe pataki

Bakare dije fun ipo aarẹ pẹlu Muhammadu Buhari ni ọdun 2011, gẹgẹ bi igbakeji. Ṣugbọn, wọn ko wọle.

''Bi orileede wa ti se ri yí, ẹnikẹni to ba fẹ dupo aarẹ gbọdọ joko, ko fi ọrọ jomitooro ọrọ pẹlu awọn ara Ariwa Naijiria ni.

"Igbagbọ awọn eniyan Ariwa Naijiria ni pe awọn lo nii ọbẹ ati iṣu lọwọ bi eeyan ba fẹ di aarẹ Naijiria.

Ki eleyi to yi pada, ayafi ti atunṣe ba ba iwe ofin Naijiria taa n lo yii.''

Àkọlé fídíò, Ooni: A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa

O tẹsiwaju pe nigba aye awọn olori Naijiria bi Ahmadu Bello, ti awọn ileeṣẹ n ṣiṣẹ daadaa, ti nkan si rọsọmu fawọn ara àríwá, ti kọja.

''Ni bayii, ohun tawọn ara ariwa ni, naa ni ipo ati agbara ìjọba. Wọn o si ni fẹ fi silẹ lẹrọ''

Bakare ni laarin awọn ara eeyan Yoruba tabi awọn ariwa gan, ko si ẹni to le da jawe olubori ninu idibo, bi wọn ko ba fọwọ wẹwọ.

Lori bo se ri iṣejọba awọn to wa lori aleefa bayi laarin ọdun mẹfa to kọja, Bakare ni nkan ti bajẹ jinna lai naani pe ijọba n ṣa gbogbo ipa to le ṣa.

''Afojusun wa lọdọ ijọba ga gan. Mo maa n ro nigba mii pe ṣe kii ṣe pe aarẹ Buhari ti sọ ara rẹ di ope loju araalu nitori igba to fẹ du ipo yii, wọn ro pe ohun gbogbo lo le ṣe''

Ojisẹ Ọlọ́run naa tun mẹnuba bi ailera ti ṣe ṣe idiwọ fun Buhari ni saa kinni rẹ.

O ṣalaye pe ''ogo Olorun ni Buhari ṣi fi wa laye. Bi a ba pa gbogbo ọdun mẹfa to lo papọ, yatọ si nkan amayedẹrun to ri ṣe diẹ, gbogbo ileri to ṣe faraalu nipa Boko Haram ati ààbò, pabo lo ja si''

Bakare wa ni oun ko ni fọwọ gbaya tabi ṣe ileri kankan pe oun dara ju ẹlomiran lọ ayafi toun ba de ori ipo toun si ṣe daada ju awọn to wa nibẹ lọ.

O ni ni toun o, oun ko ni pe funfun ni dudu nitori pe nnkan naa ni ohun ṣe pẹlu ọrẹ tabi ẹni mimọ.