eNaira: CBN figbe ta lorí àwọn gbájúẹ̀ tó fẹ́ lu aráàlú ní jìbìtì lójú òpó eNaira lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, cbn
Banki apapọ Naijiria, CBN, ti fi ikilọ sita fun awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn o ṣọra fun awọn onijibiti to n fi iroyin sita nipa owo eNaira ti wọn ṣe ifilọlẹ rẹ laipẹ.
Oludari ẹka iroyin ni CBN, Ọgbẹni Osita Nwanisobi sọ ninu atẹjade kan to wa lori ayelujara banki naa pe awọn onijibiti kan fi iroyin sita pe CBN n pin owo kọrẹnsi ni ọfẹ lati ipasẹ oju opo eNaira fun araalu.
Ọjọ Aje, ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021 ni Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ifilọlẹ owo ori ayelujara naa nilu Abuja.
Àwọn iròyin tì ẹ le ní ìfẹ̀ síí:
- Wo bí o ṣe le ná owó eNaira tí Naijiria fẹ́ ẹ̀ má lò báyìí
- Ṣé o tí gbọ́ nípa eNaira, owó àìrí tuntun tí CBN ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀? Nkan tí ó ní láti mọ̀ rèé
- Wọ́n gbé ọmọ mi tó jẹ́ Babaláwo Sunday Igboho, a kò mọ ìrìn rẹ̀ láti oṣù mẹ́ta
- Ìwà ìkà sí Yorùbá ni bí ìjọba ṣe ti bodè Seme láti 2019 - Gani Adams
- "Ẹlẹ́wọ̀n Abolongo pa méjì lára ọdẹ ìbílẹ̀ lásìkò tà ń ṣà wọ́n kiri ìgboro Oyo"
- "Àwa ológun fipá gbàjọba ní Sudan láti dènà ogun abẹ́lé ni"
- Ọmọ onílẹ̀ mẹ́ta kó sí páńpẹ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn
Ọgbẹni Nwanisobi sọ pe oju opo ayelujara Twitter ni onijibiti naa pẹlu orukọ @enaira_cbdc ti n fi ayederu iroyin sita.
O ni niṣe ni awọn onijiti naa kọ ọ sibẹ pe CBN n pin aadọta biliọnu eNaira lọfẹẹ fun araalu.
Ti wọn si ti n lu awọn eeyan ni jibiti pẹlu oju opo 'link' ti wọn fi sibẹ pe ki awọn eeyan tẹ lati kọwe beere fun owo ti wọn.
Nwanisobi sọ pe ori ayelujara ibaraẹnidọrẹ Facebook ati Instagram nikan ni CBN n lo fun eNaira, pẹlu orukọ www.facebook.com/myenaira; www.instagram.com/myenaira.
Bakan naa lo ni awọn eeyan le lọ si itakun agbaye www.enaira.gov.ng tabi pe 080069362472 fun alaye ati itọni nipa eNaira.
Ninu iroyin miran, oriṣiriṣi awuyewuye lo ti n waye lori ọrọ owo eNaira, paapaa lati Ọjọru.
Idi ni pe 'App' ti awọn eeyan fi n na owo naa, eNaira Wallet, ti poora lori ayelujara Google Playstore.
Ṣaaju ko to o poora, o ti le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan to ti gbà á si ori foonu wọn fun lilo.
Agbẹnusọ banki apapọ, Osita Nwanisobi sọ pe wọn yọ 'App' naa kuro lori ayelujara fun atunṣe to yẹ.




















