2023 Election: Mimiko padà sí PDP lẹ́yìn ìpàdé ìdákọ́ńkọ́ pẹ̀lú Seyi Makinde, Nyeson Wike l'Ondo

Oríṣun àwòrán, daily post
Gomina ipinlẹ Ondo nigba kan, Olusegun Mimiko ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.
Lasiko ti awọn gomina kan lati inu ẹgbẹ PDD, ṣe abẹwo si ile oloṣelu naa to wa ni ilu Ondo, nipinlẹ Ondo, ni Ọjọbọ, ni eyi waye.
Awọn gomina naa ni Aminu Tambuwal lati Sokoto, Okezie Ikpeazu lati Abia, Nyesom Wike lati Rivers, ati Seyi Makinde lati Oyo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Obìrin tó ń ta omi inú ọ̀rá subú pẹ̀lú ọmọ lẹ́yìn torí ebi
- Ẹ ṣì mí gbọ́ ni, a nílò ìrànwọ́ àwọn ìjọba ìpinlẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n - Aregbesola
- Wo orúkọ tuntun tí Facebook yóò má jẹ́ láti àkókò yíì lọ
- Wọ́n gbé ọmọ mi tó jẹ́ Babaláwo Sunday Igboho, a kò mọ ìrìn rẹ̀ láti oṣù mẹ́ta
- Ọkùnrin kan wọ gàù torí ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ sí aya aláya lórí Whatsapp
- "Ẹlẹ́wọ̀n Abolongo pa méjì lára ọdẹ ìbílẹ̀ lásìkò tà ń ṣà wọ́n kiri ìgboro Oyo"
- Ìwà ìkà sí Yorùbá ni bí ìjọba ṣe ti bodè Seme láti 2019 - Gani Adams
Koko abẹwo awọn gomina naa si ni lati bẹ Mimiko pe ko darapọ mọ ẹgbẹ wọn.
Ṣaaju asiko yii, ọmọ ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party, ZLP, ni Mimiko jẹ.
Yatọ si pe Segun Mimiko darapọ mọ PDP bayii, awọn alẹnu-lọrọ ninu ẹgbẹ ZLP lati ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinll Ondo lo tun darapọ mọ PDP pẹlu rẹ.
Awọn olori ẹgbẹ ZLP naa sọ pe awọn gbà lati darapọ mọ PDP "nitori pe igbesẹ naa yoo gba Naijiria kuro lọwọ ijọba APC, ti yoo si tun fi ẹsẹ rẹ si oju ọna alaafia ati ilọsiwaju".
Igba kẹta re e ti Olusegun Mimiko yoo fi ẹgbẹ oṣelu kan silẹ lati darapọ mọ PDP.
Ọmọ ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy, AD ni lọdun 1999, to si ṣe kọmisanna eto ilera ipinlẹ Ondo labẹ ijọba Adefarati.
O darapọ mọ ẹgbẹ PDP lẹyin naa, to si ṣe minisita labẹ ijọba Olusegun Obasanjo.
O tun fi PDP silẹ lati darapọ mọ Labour Part, nibi to ti dupo gomina to si wọle, ṣugbọn ko to o pari saa rẹ lo tun ti pada si PDP.
Lẹyin naa lo tun lọ si ZLP nibi to ti dupo sẹnetọ ni 2019, ṣugbọn o ni ijakulẹ.

Gómìnà PDP mẹ́rin lọ fa ojú Mimiko mọ̀ra l'Ondo

Oríṣun àwòrán, Sam Olusegun
Gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹri, Olusegun Mimiko ti gbalejo gomina mẹrin latinu ẹgbẹ oselu PDP ni ile rẹ ni ipinlẹ Ondo.
Eyi ko ṣẹyin iroyin pe Mimiko ti ṣetan lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP lorilẹede Naijiria.
Awọn Gomina to wa ṣepade pẹlu rẹ ni gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, gomina ipinlẹ Rivers, Nyeson Wike, Gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal ati gomina ipinlẹ Abia, Okezie Ikpeazu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wọ́n gbé ọmọ mi tó jẹ́ Babaláwo Sunday Igboho, a kò mọ ìrìn rẹ̀ láti oṣù mẹ́ta
- Seyi Makinde kò láṣẹ láti fi ẹ̀rọ CCTV sí ọgbà ẹ̀wọ̀n - Aregbesola
- Ọkùnrin kan wọ gàù torí ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ sí aya aláya lórí Whatsapp
- "Ẹlẹ́wọ̀n Abolongo pa méjì lára ọdẹ ìbílẹ̀ lásìkò tà ń ṣà wọ́n kiri ìgboro Oyo"
- Ṣé lóòtọ́ ni CBN n pín àádọ́ta bílíọnù eNaira lọ́ọ̀fẹ́ fún aráàlú?
- "Àwa ológun fipá gbàjọba ní Sudan láti dènà ogun abẹ́lé ni"
- Ìwà ìkà sí Yorùbá ni bí ìjọba ṣe ti bodè Seme láti 2019 - Gani Adams
- Ọmọ onílẹ̀ mẹ́ta kó sí páńpẹ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- Wo ohun tí Yinka Alaseyori sọ nipa Tope Alabi ní àyájọ̀ ọjọ́ ìbí rẹ̀
- Ọmọ onílẹ̀ mẹ́ta kó sí páńpẹ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn
Wẹrẹ ti awọn gomina naa de si ile rẹ ni ilu Ondo, ni wọn wọ iyẹwu lọ lati lọ ṣe ipade.
Saa keji ijọba Mimiko nigba to wa ni ipo gomina, lo fi ẹgbẹ oselu Labour Party silẹ lati lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Amọ o pada si ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party- ZLP ki idibo sipo gbogboogbo to waye, nibi to ti dije dupo sẹnatọ ni ẹkun Guusu Ondo, ti Sẹnatọ Ayo Akinyelure ti ẹgbẹ oṣelu PDP si fi ẹyin rẹ janlẹ.
Bakan naa lo ṣe atilẹyin fun igbakeji gomina nipinlẹ Ondo tẹlẹ, Agboola Ajayi lasiko to dije gomina lẹgbẹ oselu ZLP nipinlẹ Ondo to si fi idi rẹmi.
Iroyin ni lati igba ti wọn ti kede pe o ṣeeṣe ko pada si ẹgbẹ oṣelu PDP ni awọn kan ninu ẹgbẹ naa ti n fi apa janu.
Laipẹ yii ni Aarẹ ile Igbimọ Aṣofin tẹlẹri, to jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Bukola Saraki fi lede pe gomina tẹlẹri kan yoo darapọ mọ PDP laipẹ, ti awọn kan si sọ wi pe o ṣeeṣe ko jẹ Mimiko.
















