Jim Mattis wo awoyanu ọmọogun Indonesia to nmu ẹjẹ ejo

Awọn ọmọogun Indonesia nfi ejo sere.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọogun Indonesia nfi ejo sere gẹgẹbii ara igbaradi wọn.

Minisita feto abo ni ilẹ Amẹrika, Jim Mattis ti sọ wipe oun ri awọn ọmọogun ilẹ Indonesia kan ti wọn nmu ẹjẹ ejo ti wọn si n fi ori fọ bulọọku ikọle lọjọọru.

Minisita Jim Mattis ni bakannaa ni awọn miran n yiira ninu eefọ igo ti wọn se gẹgẹbi ara afihan iwa akin awọn ọmọogun ilẹ Indonesia.

Minisita feto abo nilẹ Amẹrika, Jim Mattis ati akẹgbẹ rẹ nilẹ Indonesian, Ryamizard Ryacudu se ayẹwo awọn ọmọogun ilẹ Indonesia.

Minisita feto abo nilẹ Amẹrika, Jim Mattis ati akẹgbẹ rẹ nilẹ Indonesian, Ryamizard Ryacudu se ayẹwo awọn ọmọogun ilẹ Indonesia.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Inu Minisita fọrọ abo ni ilẹ Amẹrika dun si igbaradi naa eleyi ti wọn fi kasẹ abẹwo ọlọjọ mẹta to se si orilẹede Indonesia nilẹ

Ki se igba akọkọ niyi fun awọn eekan nileesẹ ọmọogun ilẹ Amẹrika lati ri awọn isẹ igbaradi awọn ologun ti wọn rinrinajo lọ si ilẹ okeere, amọ awọn igbaradi bii kikoju awọn ajinigbe lawọn ikọ oniroyin to ba minisita ilẹ Amẹrika naa kọwọrin nreti.

Eto igbaradi yii waye ni olu ileesẹ ọmọogun ilẹ Indonesia pẹlu ọpọlọpọ awọn igbaradi miran ninu eyi ti wọn ti fi asọ dudu bo oju ọmọogun kan pẹlu ibọn lọwọ lati yin si ohun kan ti wọn gbe si aarin ẹsẹ ọkan lara awọn akẹgbẹ rẹ.

Awọn ọmọogun ilẹ Indonesia tun nrin lori ina

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọogun se ohun iyalẹnu fun minisita feto abo ni ilẹ Amẹrika

Lẹyin ti wọn pari oniruuru awọn eto igbaradi yii tan ni wọn gunle igbaradi lorii kikoju awọn ajinigbe pẹlu aja ọlọpaa ati baluu.

Inu Minisita fọrọ abo ni ilẹ Amẹrika dun si igbaradi naa eleyi ti wọn fi kasẹ abẹwo ọlọjọ mẹta to se si orilẹede Indonesia nilẹ.

Minisita feto abo nilẹ Amẹrika, Jim Mattis ati aarẹ ilẹ Indonesian, Joko Widodo nbọwọ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Mattis gbe osuba nla fun awọn ọmọogun ilẹ Indonesia paapaa pẹlu bi wọn se nfi ọgbọn mu awọn ejo naa ki to pa wọn ti wọn si mu ẹjẹ wọn.

Ọgbẹni Mattis gbe osuba nla fun awọn ọmọogun ilẹ Indonesia paapaa pẹlu bi wọn se nfi ọgbọn mu awọn ejo naa ki to pa wọn ti wọn si mu ẹjẹ wọn.

"Ọpọ isẹ ati igbaradi ni wọn se ki wọn to lee da ara ti wọn da. Ki awọn ọmọogun to lee se iru ohun ti wọn gbe se, pẹlu bi wọn se se e ni sisẹ n tẹle, o di dandan pe wọn lee gbe nkan ribiribi se.

Nibayii, erongba orilẹede Indonesia ni pe Minisita feto abo ni ilẹ Gẹẹsi, Jim Mattis yoo lee se atọna bi okun ajọsepọ laarin orilẹede naa pẹlu ilẹ Amẹrika.