Ooni Ile Ife: Màmá tó bí ìyá Ọọ̀ni ilé Ifẹ̀ ju awà sílẹ̀ lẹ́ni ọdún 103

Ooni Ogunwusi ati mama faramọbi

Oríṣun àwòrán, MOses olafare

Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji ti padanu Iya-iya rẹ, iyaafin Comfort Faramọbi Ajọkẹ Ọlasọji Sọji-Ọpa.

Agbẹnusọ fun Aafin ile Oodua, Moses Ọlafare to fidi eyi mulẹ ni aṣalẹ ọjọ Aiku ṣalaye pe ẹni ọdun mẹtalelọgọrun ni iya naa ki ọlọjọ to de.

Iya-iya Ọọni Ogunwusi, ti ọpọ mọ si 'Mama Agba'nigba aye rẹ ni wọn ṣalaye pe o jẹ gbajums oniṣowo ti wọn bi ni ọdun 1907 si idile Oloye Aina Akinyẹmi ni agboole Ajigbayin ni ilu Ile Ifẹ.

Awọn ohun jijẹ ni ilu mọ iya naa fun nigba ṣango ode rẹ ti ko si si ẹni ti ko fẹrẹ maa mọọ ni ọja Itaakọgun, Ọja titun atawọn ọja miran ni ilu Ile Ifẹ ati agbegbe rẹ.