Oluyemisi Orisabiyi: Ẹ̀ẹ̀mẹta péré làwọn òṣìṣẹ́ KAI bẹ̀ mí wò, mo kọ̀wé sí wọn lái rí èsì

Àkọlé fídíò, Oluyemisi Orisabiyi: Ẹ̀ẹ̀mẹta péré làwọn òṣìṣẹ́ KAI bẹ̀ mí wò, mo kọ̀wé sí wọn lái rí èsì

Adura ti ọpọ ẹda maa n gba lojoojumọ to ba n jade lọ ni pe ka ma rin arinfẹsẹsi, ka ma ko ijamba lẹnu irinajo wa.

Amọ ni ọjọ ti ijamba yoo ba waye, gaga ni ara ẹda maa n ya.

Ọjọ si ni ọjọ kan ninu osu kẹwa ọdun to kọja nigba ti alagba Oluyemisi Orisabiyi jade amọ to sadede ko agbako ijamba lojiji.

Lati igba naa si ni ara ko ti rọ okun, rọ adiẹ fun baba naa tii se ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin pẹlu awọn eeyan to n se itọju wọn.

Bawo ni Orisabiyi se ko ijamba to ba ẹsẹ rẹ?

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ nipa ipo to n la kọja, Orishabiyi ni aburo iyawo oun ni ọkọ rẹ ku, ti oun si ni ki oun lọ ki wọn ku ara fẹra ku.

O ni bi oun se n sọda titi marose Oshodi si Abule Egba ni adugbo Iyana Ipaja, ti oun si de opopona ti wọn ya sọtọ fun ọkọ bọọsi ijọba, ni mọto tẹ ẹsẹ oun.

Orishabiyi ni ọkan lara awọn mọto ileesẹ to n se akoso ayika nipinlẹ Eko, ti wọn n pe ni KAI lo tẹ ẹsẹ oun.

O ni lati igba naa ni oun ti wọ wahala, ti jijẹ mimu si di ogun nla.

Ebi n pa mi, iya n jẹ mi, ko si owo lọwọ mi:

Nigba to n salaye ohun ti oju rẹ ti ri lati igba ti ijamba naa ti waye, Orishabiyi ni isoro nla ni jijẹ mimu jẹ fun oun lati igba naa.

O sọ fun BBC Yoruba pe ẹẹmẹta pere lawọn osisẹ Ajọ KAI to fi mọto kan oun lẹsẹ wa yọju wo oun lati beere alaafia oun, ti oun ko si gburo wọn mọ.

O ni owo ribi ribi ni oun n na lati se itọju ara oun, ti ko si si kọbọ lọwọ oun mọ lati maa setọju ẹsẹ naa siwaju.

Baba agba naa salaye pe oun ti kọwe si ajọ KAI lati beere fun eto iranwọ amọ wọn ko tii fesi si ibeere oun.

O wa ke gbajare pe ebi n pa oun, iya n jẹ oun laisi oluranlọwọ kankan.

Iha wo ni ajọ KAI kọ si isẹlẹ yii:

Wọn ni ka maa wadi ohun gbogbo daju, ka si di eyi tii se otitọ mu.

Ọna lati fidi otitọ mulẹ nipa isẹlẹ naa lo mu ki BBc Yoruba kan si ajọ KAI nipa ijamba to de ba Orisabiyi.

Nigba to n ba wa sọrọ, ọga agba fun ajọ KAI, arabinrin Gbemisola Akinpelu salaye pe lootọ ni isẹlẹ naa waye.

O ni awọn lọ wo baba naa nile iwosan lati beere alaafia rẹ, ti oun si sọ fun dokita to n setọju rẹ pe ko kọwe lorukọ̀= baba naa nipa ijamba ọhun.

Akinpelu ni iwe naa ni wọn fi n beere iranlọwọ lọdọ ileesẹ to wa fun ọrọ ayika.

O wa kede pe Kọmisana fun ọrọ ayika nipinlẹ Eko, Tunji Bello ti fọwọ si pe ki wọn san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (N500,000) fun Orisabiyi lati fi setọju ara rẹ lati bii osu kan sẹyin.

Amọ o ni o seni laanu pe awọn ko mọ ile baba naa, nọmba foonu ọmọ rẹ, ti awọn si maa n pe ni ko lọ mọ rara.