Kemi Remi Dairo: Iṣẹ́ abẹ nínú ọpọlọ àti ẹ̀rọ ni mo fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ báyìí

Àkọlé fídíò, Kemi Dairo: Iṣẹ́ abẹ nínú ọpọlọ àti ẹ̀rọ ni mo fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ báyìí

Igba laye, to ba lo siwaju, a tun lo sẹyin, ko si si ẹni to wa laye, to kọja adanwo.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu obinrin kan, Kemi Remi Dairo tii se abani se kokari ayẹyẹ, ti eti rẹ sadede di lẹyin to ti ibi inawo kan de.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Kemi Dairo ni ariwo nla kan lo jade lati inu speaker nibi inawo naa, ti eti oun si ho, lai mọ pe ijamba ti se oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Obinrin naa salaye siwaju pe awọn ọmọ oun maa n kọ ọrọ wọn silẹ fun oun lati ka, ti ọkọ oun si maa n kọ tiẹ sinu foonu, ki oun lee mọ ohun to fẹ.

Ọpẹlọpẹ isẹ abẹ ninu ọpọlọ ati ẹrọ igbalode kan, to gba Kemi silẹ lọwọ ipenija eti didi, eyi to fi n gbọrọ bayi .