Ọkùnrin kan tí àwọn agbébọn kọlù ní Nasarawa sọ ìrírí rẹ̀

Arakunrin abani tun ọkọ sẹ kan ti sọ iriri bi awọn agbebọn ṣe pade rẹ lọna, ti wọn si ge ọwọ rẹ mejeeji.
Yahaya Muhammed Galadima sọ pe ni nkan bi aago mẹjọ alẹ lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2021, ni awọn ọkunrin marun-un da a duro lasiko to n pada sile lẹyin iṣẹ oojọ rẹ ni ipinlẹ Nasarawa, ti wọn si bẹrẹ si ni fi igi lu u.
O ni lasiko ti oun n gbiyanju lati fi ọwọ daabo bo ori oun lọwọ àdá ti ẹnikan lara wọn fi n na oun, lo ni wọn fi ada ge ọwọ mejeeji.
Nigba to n ba BBC Pidgin sọrọ pẹlu omije loju, Galadima sọ pe oun n pada si ilu Lafia to jẹ olu ilu ipinlẹ naa, lati abule Yelwa nijọba ibilẹ Doma, nibi to ti lọ tun ọkọ bọọsi kan sẹ, ni iṣẹlẹ naa waye.
Ọgbẹni Galadima sọ pe wọn ti kọkọ gba ọkada oun, foonu ati owo to wa lọwọ oun.
Bi wọn ṣe fi ada ge ọwọ rẹ mejeeji tan ni wọn salọ.
Ọpẹlọpẹ ọmọ iṣẹ rẹ ti wọn jọ n lọ lo ke gbajare ti awọn ara abule fi sare gbe lọ sileewosan Dalhatu Araf nilu Lafia.
O ni "o n ba mi ni ọkan jẹ pe mi o ni le lo ọwọ mi mọ fun iyoku aye mi."

Oríṣun àwòrán, yahaya galadima
O ni ka ni oun mọ pe iru nkan bẹẹ yoo sẹlẹ ni, oun ko ba ma ti lọ tun ọkọ onibaara naa ṣe.
"Ireti kan ṣoṣo ti mo ni bayii ni pe Ọlọrun yoo ran mi lọwọ lati kọ iṣẹ miran ti ma a fi ma gbọ bukata mi ati ti ẹbi.".
Arakunrin mọkaliiki naa sọ pe yoo ṣoro lati tẹsiwaju ninu iṣẹ naa, nitori pe ko si ọwọ to fẹ fi ṣiṣẹ.
Owo to to ẹgbẹrun mẹwa Naira lo sọ pe oun ma n pa ni ojoojumọ. Owo naa lo si fi n tọju ẹbi rẹ.
Koda iya arakunrin ọhun to ba akọroyin sọrọ̀ ni oti tán fun oun bayii, nitori pe oun lo n tọju Galadima bi ọmọ tuntun.













