Ẹ yé fi ọ̀rọ̀ ara yín pamọ́ tí ẹ bá ń jápa nítorí... - Woli Arole

Àkọlé fídíò, Ọlọ́run kò dá ẹ̀dá ènìyàn láti wà ní ojúkan
Ẹ yé fi ọ̀rọ̀ ara yín pamọ́ tí ẹ bá ń jápa nítorí... - Woli Arole
Woli Arole

"Ọlọ́run kò dá ẹ̀dá ènìyàn láti wà ní ojúkan, ènìyàn láti máa ṣe ìrìnàjò láti ibì kan síbòmíràn."

Gbajúgbajà adẹ́rìnínpòṣónú Oluwatoyin Bayegun tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Woli Arole ti gba àwọn ènìyàn tó ń gbèrò láti kúrò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ìmọ̀ràn lórí àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ kí wọ́n máa gbé kí wọ́n tó lọ.

Ó ní ó yẹ kí àwọn ènìyàn tó bá fẹ́ ṣe ìrìnàjò kúrò ní Nàìjíríà máa bèèrè fún ìtọ́sọ́nà lọ́wọ́ Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn kí wọ́n tó gbé ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.

“Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ni kìí sọ̀rọ̀ síta nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìrìnàjò lọ sí ìlú tí wọn kò dé rí èyí sì máa ń ṣe àkóbá fún wọn lọ́pọ̀ ìgbà tí wọ́n bá dé àwọn orílẹ̀ èdè náà.”

Ki ni imọran Woli Arole nipa asiko tẹẹ ba ti de ilu Oyinbo?

Woli Arole

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń fẹ́ sá kúrò ní Nàìjíríà nítorí pé àwọn akẹgbẹ́ wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí kò dára kí ènìyàn bẹ́ sí ìrìnàjò láìní tàbí mọ nǹkan pàtó tó fẹ́ lọ ṣe ní ibi tó ń lọ.

Woli Arole tẹ̀síwájú pé ènìyàn gbọ́dọ̀ pèsè àwọn nǹkan sílẹ̀ ní ibi tó bá ń lọ kó le tètè rí ọ̀nà bá já nínú ìgbésẹ̀ rẹ̀ tó bá dé bẹ̀.

Ó ní sísa níní èròńgbà láti kàn sá kúrò ní orílẹ̀ èdè yìí tí wọ́n máa ń bá lọ sí orílẹ̀ èdè kìí ṣe nǹkan tó dára tó.

Bákan náà ló gba àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń gbèrò láti kúrò ní Nàìjíríà lọ sí orílẹ̀ èdè mìíràn láti má ṣi ìwà wù, kí wọ́n sì máa mọ ọmọ ẹni tí wọ́n ń ṣe ní gbogbo ìgbà.

“Ìwà lè gbé ènìyàn dé ọgbà ẹ̀wọ̀n láàárín oṣù mẹ́ta tí kò bá ṣọ́ra.”