Baby placenta missing in Ondo: Ìyá ọmọ sọ ohun tójú wọ́n rí pẹ̀lú àwọn nọ́ọ̀sì tó gbẹ̀bí
BBC Yoruba gbera lọ si ilu Emure-Ile ni ipinlẹ Ondo lati ba mọlẹbi Joy John Babatunde ati ọkọ rẹ ni gbolohun lori ohun to ṣẹlẹ gangan nipa iroyin olubi ọmọ to dede dawati nile iwosan.
Ninu idahun rẹ, iya ọmọ naa to jẹ ni ọdun mejidinlogun, Joy ṣalaye pe awọn tun beere lọwọ oṣiṣẹ to n tọju ile iwosan naa, o wọle o jade o si ni oun o ri olubi o.
A tun ba iya ọkọ Joy sọrọ pe ki ni oun naa mọ nipa iṣẹlẹ ọhun, alaye to ṣe ni pe: "Inu ọja ni mo wa nigba ti wọn pe wipe iyawo ọmọ mi n rọbi lọwọ, mo si gbera mo lọ sibẹ amọ ọtọ ni alaye ti wọn ko ti wọn n ro".

"Nigba ti ọkọ mi de bi mo ṣe bimọ tan ti o wọle, awọn nọọsi le e pada pe ko lọ wa nnkan ti mo fẹ jẹ wa, igba to di aarọ ọjọ keji taa fẹ maa lọ ile ni ọkọ mi beere pe bawo ni nipa olubi yẹn".
Joy iya ọlọmọ ni iya ọkọ oun ati ọkọ oun lọ sita lati lọ beere olubi yẹn, bi wọn si ṣe beere lọwọ oṣiṣẹ to n ṣetọju ilẹ, o wọle o jade o si ni oun ko ri olubi mọ.
O ṣalaye pe ati agbalẹ ati awọn nọọsi wle lọwa olubi wọn ko si ri i.
"Wọn ba bẹrẹ si ni bẹ iya ọkọ mi ati ọkọ mi pe ki wọn ma jẹ ki eeyan kankan gbọ. Wọn ka ma san owo bẹẹdi ati owo "discharge ayafi owo ogun nikan".
Joy ni iya ọkọ oun lo yari to si lọ fi ẹjọ sun ọlọpaa.
Wọn sọ fun ọlọpaa pe aja lo gbe olubi ọmọ

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya ni awọn ti n gbe igbesẹ lati rii pe ibi ọmọ naa jade ni ibikibi to ba wa.
"Ẹni to jẹ nọọsi ni ọjọ naa to yẹ ko ṣiṣẹ ni o rẹ oun, ẹlomiran lo gbẹbi ti ko si y ko ri bẹẹ.
Amọ Funmilayo Odunlami-Omisanya ni igba ti awọn ba pari iwadii, gbogbo ẹni ti ile ẹjọ ba tọ si ni yoo fi gbara.
Ẹwẹ, iya ọmọ tun tu aṣiri pe inu ibi ti oun ti bimọ, wọn tilẹkun lọjọ naa "torinaa, bi aja ṣe wọle gbe ibi ọmọ ko ye mi o!".