Àwọn àǹfààní tí Naijiria yóò jẹ nínú ìrìnàjò àkọ́kọ́ Tinubu sí France

Oríṣun àwòrán, TWITTER/@OFFICIALABAT
Ààrẹ Naijiria, Bola Tinubu ti gúnlẹ̀ si ilu Paris, orilẹ-ede France lati kopa fun ìgbà àkọ́kọ́ ninu ijiroro agbaye. Ijiroro naa ti wọn fi sọrí eto ẹnawo, ni France, Barbados ati India ṣe agbatẹru rẹ.
Lara awọn nnkan ti Ààrẹ Tinubu yoo ṣe ni Paris ni pe, yoo ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ̀ ni ipejọpọ kan lori ọna lati mu eto ibaraẹni sọ̀rọ̀, fẹsẹ múlẹ̀ si.
Lara àwọn eeyan ti yoo wa nibi ìdánilẹ́kọ̀ọ̀ naa ni David Craig lati Taskforce on Nature-related Financial Disclosures (TNFD), Mark Carney lati Glasgow Financial Alliance for Net Zero (GFANZ), Mary Schapiro lati Bloomberg, Sabine Maudere to jẹ igbakeji Network for Greening financial system, ati Catherine McKenna to jẹ asoju àjọ UN.
Gẹ́gẹ́ bi nnkan ti oludamọran pataki fun Aarẹ lori àkànṣe iṣẹ́ ati ibanisọrọ, Dele Alake, sọ, oni yii ni Tinubu yoo gba akọsilẹ nípa awọn ojúṣe Naijiria nibi ipade ijiroro naa, ati lati ṣètò ipade pẹlu awọn olori l'agbaye ati àwọn àjọ lorisirisi.
Àwọn anfaani ti Naijiria yoo jẹ nibi ipade naa
Ọgbẹni Dele Alake sọ fun awọn akọroyin pe Tinubu yoo ṣe ipade pẹlu awọn olori ni ẹka ẹnawo lagbaye, awọn àjọ orisirisi, ati aṣojú orile-ede, láti le mu ki idokoowo ilẹ̀ òkèèrè pọ̀ si ni Naijiria.
Eyi n waye lẹyin ti banki àpapọ̀ Naijiria, CBN, kede pe oun ti mu ayipada bá paṣipaarọ owo ilẹ̀ òkèèrè, lati fun awọn banki ni anfaani lati ṣe paṣipaarọ owo bo ṣe tẹ wọn lọrun sí.
Ọgbẹni Alake sọ fun ileeṣẹ iroyin Channels pe ilana ṣíṣe paṣipaarọ owo ti Naijiria n lo tẹ́lẹ̀, wà lara awọn nnkan to le awọn oludokowo lati ilẹ̀ òkèèrè kuro ni Naijiria.
Lara awọn afojusun ipade ijiroro naa tun ni dida ilana tuntun silẹ ti yoo mojuto awọn ipenija agbaye bíi igbogun ti ìṣẹ́, ayipada oju ọjọ́ ati aabo fun ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.
Ìròyìn sọ pé Olootu ijọba orile-ede Barbados, Mia Mottley, lo da àbá pipese iranlọwọ owo fun awọn orile-ede ti ayipada ojú ọjọ́ le ṣe akoba fun.
Arabinrin Mottley bu ẹnu atẹ lu ilana ti àwọn àjọ ayani lowo ṣe n ya awọn orile-ede to kù díẹ̀ káàtó fún lowo, to si pe fun dida èlé duro lori gbese ti awọn orile-ede naa ba fi koju wahala ayipada ojú ọjọ́.
Ti wọn ba fi fọwọ́ si eyi nibi ìjíròrò naa, owo yoo wà síi fun Naijiria lati mojuto awọn ìṣẹ̀lẹ̀ bi omiyale.
Lara àwọn àjọ agbaye ti ireti wa pe yoo kopa nibi eto naa ni Africa Development Bank Group, olórí àjọ okoowo lagbaye, Ngozi Okonjo Iweala ati bẹẹ bẹẹ lọ.














