Iná jó ọjà pákó ní ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, channelstv.com
Ijamba ina ṣẹlẹ ni ọja pako, Oluṣesi ni ilu Ado-Odo, nijọba ibilẹ Ọta ni ipinlẹ Ogun.
Ina to jo ja pako Oluṣesi naa bẹrẹ ni nnkan bii agogo mejila owurọ ni Ọjọbọ.
Awọn ontaja lọja naa sọ pe ina manamana to ṣe segesege ni ọkan lara awọn ṣọọbu itaja to wa nitosi ja naa lo ran wa si ọja pako naa.
Awọn eeyan agbegbe naa ṣalaye pe irufẹ ajalu yii ti waye ri ni nnkan bi ọdun meji sẹyin.
Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ ijamba ina naa sọ pe nṣe lawọn ọlọja lọja naa n sa kijokijo lati doola ọja wọn bi o tilẹ jẹ pe awọn oṣiṣẹ panapana de lasiko.
Ninu atẹjade ti alukoro ajọ to n pana pajawiri lorilẹede Naijiria, lẹkun Eko ati ogun, Ibrahim Farinloye fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Bakan naa ni ileeṣẹ panapana ipinlẹ Ogun fi idi iṣẹlẹ yii mulẹ.
Ko si ẹmi kankan to ba ijamba ina naa rin, biotilẹ jẹ pe ko tii si ẹni le e sọ ni pato iye owo ori awọn ọja to ṣofo sinu ina naa.








