Tinubu, Atiku, Obi, CAN, àwọn gómìnà ránṣẹ́ ọdún àjíǹde s’áwọn èèyàn Naijiria

Oríṣun àwòrán, Collage
Oni, ọjọ Kọkanleọgbọn, oṣu Kẹtani ọdun ajinde ti ọdun 20-24 bọ si .
Bi ọdun Ajinde ṣe gbode kan, Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Bọla Tinubu, ẹgbẹ awọn Kristẹni ni Naijiria, Christian Association of Nigeria, (CAN), atawọn eekan ilu mii ti n fi ọrọ ikini ku ọdun ranṣẹ sawọn eeyan orilẹ ede yii.
Bakan naa ni Abubakar Atiku, Peter Obi, awọn gomina ati ẹgbẹ oṣelu PDP ti fi ikini ọdun ati amọran ranṣe sawọn ọmọ Naijiria.
Atẹjade Tinubu ti agbẹnusọ rẹ, Ajuri Ngelale fi sita, ṣalaye pe ifarajin Jesu Kristi fun ọmọ eniyan, jẹ ẹkọ pataki fawọn olori Naijiria ati gbogbo araalu lati kọṣe.
Aarẹ kede ifẹ ati aanu lasiko yii fun gbogbo eniyan pata.
CAN
Ninu atẹjade ikini ku ọdun ti Aarẹ CAN, Archbishop Daniel Okoh fi sita lo ti ṣalaye pe ọdun Ajinde ki i ṣe fun pọpọṣinṣin nikan, bi ko ṣe lati mura siṣẹ fun sinsin Ọlọrun ati ọmọniyan
Okoh fi akoko ọdun yii rọ awọn to wa ni ipo aṣẹ lati gbajumọ iṣẹ ti araalu gbe le wọn lọwọ.
O ni kawọn olori ni gbogbo ẹka oṣelu tẹle ẹkọ ti ọdun Ajinde ko sinu, iyẹn ireti-ọ̀tun, irapada ati ironupiwada kuro ninu okunkun lọ si imọlẹ
Atiku Abubakar : Ẹ kọ́ṣe ìfẹ́ àti ìfarajìn Jesu
Igbakeji olori-orilẹ-ede Naijiria nigba kan, Atiku Abubakar naa ranṣẹ ikini ku ọdun sawọn ọmọ Naijiria lọdun Ajinde.
Atẹjade Atiku ṣalaye pe ifẹ ati ifarajin ṣe pataki fun iṣọkan Naijiria lasiko yii, nigba ti imọtara-ẹni-nikan ẹya fẹ fa ipinya.
Atiku rọ awọn olori Naijiria lati fi asiko ọdun ronu lori iṣẹ wọn si araalu.
Peter Obi náà kí àwọn Kristẹni
Oludije ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour ni 2023, Peter Obi naa fi ikini ranṣẹ sawọn Kristẹni loju opo X rẹ.
Obi gba awọn ọmọ Naijiria nimọran pe ki wọn ma sinmi ninu ilakaka wọn.
O ni eyi ni yoo mu Naijiria to dara ju lọ waye. O ni ki wọn fi ọdun Ajinde bẹ Oluwa fun idasi lati ọrun wa.
Gómìnà Edo kí àwọn Kristẹni, Adeleke pín ìrẹsì l’Ọ́ṣun, Dapọ Abiọdun s’okùn ààbo le l’Ógùn

Oríṣun àwòrán, Facebook
Bakan naa lawọn Gomina kaakiri ipinlẹ Naijiria ti ba awọn Kristẹni ati gbogbo ọmọ Naijiria yọ ayọ ọdun Ajinde.
Gomina Edo, Godwin Obaseki, rọ awọn Kristẹni lati ronu lori ikọni Ajinde.
O rọ wọn lati ma ṣe sọ ireti nu bi ọrọ aje ṣe n dẹnukọlẹ.
Ni ti Gomina Ademọla Adeleke nipinlẹ Ọṣun, irẹsi ti yoo wulo fawọn eeyan ilu naa lasiko ọdun Ajinde ati Itunu-Aawẹ ni iroyin sọ pe gomina pin.
Bẹẹ ni Gomina Dapọ Abiọdun ipinlẹ Ogun paṣẹ fawọn ọlọpaa ipinlẹ naa pe ki kaluku di agbegbe rẹ mu giri.
Gomina sọ pe ko gbọdọ si iwa ọdaran kankan b’ọdun Ajinde ṣe n lọ .
Gomina Enugu, Peter Mbah, ti Bayelsa, Douye Diri naa kede alaafia fun gbogbo ọmọ Naijiria.
Wọn ni bi nnkan tiẹ ri bakan lasiko yii, yoo pada daa pẹlu ireti ati igbagbọ, nitori Naijiria yii ko kọja atunṣe.

PDP náà kéde ìfẹ́
Ẹgbẹ oṣelu alatako fun APC, iyẹn Peoples Democratic Party (PDP), ni kawọn eeyan Naijiria kẹkọọ nipa Ajinde Jesu Kristi.
PDP ni ki wọn fifẹ han, ki wọn si mura si isọdọtun orilẹ-ede yii.
Akọwe apapọ fun PDP, Debo Ologunagba, rọ awọn eeyan lati ma ṣe sọ ireti nu lasiko ti nnkan nira yii.
Wọn ni ọjọ iwaju ologo n bẹ niwaju.














