Bàbá àti ọmọ lu ìyàwó alábàgbé pa nítorí tábìlì ní ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, OMOLOLA ODUTOLA,
Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ ogun ti tẹ baba ati ọmọ ti wọn ṣekupa iyawo alabagbe wọn kan.
Iroyin ni tabili kan ti oloogbe naa, Tope Owoade, fi n ta pọnmọ lo fa ija laarin wọn, eyii to yọri si iku obinrin naa.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ogun, Omolola Odutola fi lede, o ni ija naa bẹrẹ latari pe oloogbe ọhun ko fẹ ki wọn maa joko sori tabili ti oun fi n taja.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọkọ oloogbe ẹni ọdun mẹtalelogoji naa, Isiaka Owoade, lo fi ọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti.
Bi ija naa ṣe bẹrẹ
Olọpaa ni ọkọ oloogbe naa ṣalaye pe ni nkan bii aago mẹwaa abọ alẹ ni awọn afurasi mejeji, Chizoke Obiadada, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelaadọta ati ọmọ rẹ, Micheal Obiadada, to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun lu iyawo oun nilu bara lẹyin to dẹkun wọn ati maa joko sori tabili ọja rẹ.
O ni “Lilu naa pọ to bẹe ti ẹjẹ fi n jade lati inu ile ọmọ ati loju ara rẹ.
“O ṣalaye pe wọn gbe iyawo oun digbadigba lọ sile iwosan Main Frame to wa ni Atan Agowa nibi ti wọn ti kọ ọ.
“O pari ọrọ rẹ pe asiko ti wọn n gbe iyawo oun lọ sile iwosan ijọba lo jẹ Ọlọrun nipe.”
Odutola ṣo pe ni kete ti ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti ni wọn fi ṣikun ofin mu awọn afurasi ọhun, iwadii si ti bẹrẹ.
Alukoro ọlọpaa naa sọ siwaju si pe awọn yoo tare ẹjọ ọhun lọ si ẹka to n ṣe iwadii iwa ọdaran, CID, laipẹ.
O pari ọrọ rẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti n gbe igbesẹ lati gbe oku naa lọ sile igbokupamọsi OOUTH to wa ni niluu Sagamu fun itẹseiaju iwadii ẹjọ ọhun.














