Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn tí afurasí sọ́jà gún òǹtajà lọ́bẹ pa l'Ondo

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X
Rogbodiyan bẹ silẹ niluu Akure nipinlẹ Ondo lọjọ Abamẹta nigba ti afurasi sọja kan gun ontaja, Ezeani Ebuka lọbẹ pa.
Kete ti iṣẹlẹ yii waye l'awọn ontaja bẹrẹ iwọde lopopona Arakale niluu Akure lati fi ẹhonu wọn lori iṣekupani akẹgbẹ wọn.
Awọn ontaja naa di opopona yii nibi ti wọn ti n beere fun idajọ ododo lori iku Ebuka, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn.
Bi wakati meji ọtọtọ ni ọkọ tabi alupupu ko fi le kọja lopopona ọhun.
Awọn o ṣoju mi koro kan ṣalaye pe niṣe l'awọn sọja ṣadeedee ya wọ inu ọja lẹyin ede aiyede to ṣẹlẹ laarin ọkan ninu wọn ati ontaja kan nigba ti o fẹ sanwo ọja to ra.
Wọn ni asiko yii ni sọja naa gun Ebuka lọbẹ ti o si ku lẹsẹkẹsẹ.
Ọkan lara awọn adari ọja ọhun to bawọn akọroyin sọrọ ṣapejuwe iṣẹlẹ naa bi eyi to ba ni lọkan jẹ.
O rọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun lati ṣe awari sọja naa, ki wọn si fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.
Awọn ọlọpaa ni ko jẹ ki iṣẹlẹ ọhun di nnkan mii, lẹyin ti wọn ṣí opopona t'awọn ontaja ti n ṣe ifẹhonuhan pada.
Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmi Odunlami fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Odunlami sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa n ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ ologun bayii lati ṣawari afurasi sọja naa ki ileeṣẹ ọlọpaa le fi ọwọ ofin mu un.















