EFCC mú afurasí Alfa àti Babaláwo fẹ́sun lílu olóṣèlú kan ní jìbìtì N24m

Oríṣun àwòrán, EFCC/INstagram
Ọjọ́ gbogbo ní ti olè, àmọ́ ọjọ́ kan ṣoṣo pere ni ti olohun.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu afurasi Alfa àti Babalawo kan nigba ti ọwọ ajọ EFCC tẹ wọn lórí ẹsun pe wọn lu oloselu kan ni jìbìtì.
Orúkọ awọn afurasi mejeeji naa ni Alfa Abiodun
Àwọn afurasi naa si ni wọn fẹ́sun kan pe wọn gba Oludije sipo ile asoju-sofin kan ni ìpínlẹ̀ Ekiti.
Iroyin kan tí àjọ EFCC fisita loju opo Instagram rẹ lo sisọ loju iṣẹlẹ naa fun araye.
Atejade naa ni owo to le díẹ̀ ni mílíọ̀nù lọ́nà mẹ́rinlelogun naira sì (N24, 071,000) ni EFCC fẹsun kan pe wọn gba lọwọ oloselu náà.
Owo naa si ni awọn afurasi oníjìbìtì naa ni awọn yoo lo lati fi ba oloselu naa wa agbara lori ipo to n du.
Awọn afurasi mejeeji naa si lo jẹwọ pe lootọ ni awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn naa.

Oríṣun àwòrán, EFCC/Instagram
Lootọ ni mo gba owo lọwọ oloselu naa – Adifala
Nigba to n ka boroboro fun EFCC, Babalawo Adifala ni lootọ ni òun gba owo lọwọ oloselu naa.
O ni lara owo tòun gba ni N2. 9m eyi ti oun lo lati ra eroja fun etutu bíi maalu dúdú, aláwọ̀ esuru àti funfun.
Bakan naa lo ni oun tun ra ọpọlọpọ agbo, turari, òrùka àti bẹẹ bẹẹ lọ.
“Kódà, mo tun kan si Ifawole Ajibola lori ọrọ yii, ta si dijọ ṣe etutu naa papọ, titi tí àwọn EFCC fi wa mu wa”
Emi ni mo kọkọ mọ oloselu náà, ọpọlọpọ igba si ni mo gba owo lọwọ rẹ:
Alfa Ibrahim, to ni oun ni oun kọkọ mọ oloselu ti wọn lu ni jibiti salaye pe lootọ ni oun gba owo lọwọ rẹ̀ ni àìmọye igba.
“Iṣẹ́ tiwa ní pe ka ṣe adura ati awọn etutu to ṣe koko, eyi ta ṣe, ta si fi iyoku si ọwọ Ọlọrun.
Amọ nigba to ya, wọn gbe ijoko ile asoju-sofin kuro ni ilu Oye(Ekiti, lọ si Ikole-Ekiti. “
Àwọn agbébọn ṣè ìkọlù sí àgọ́ olọ́pàá ní Akure, ẹ̀mí ọlọ́pàá kan lọ si

Oríṣun àwòrán, Other
Awọn agbebọn kan ti ṣekọlu si agọ ọlọpaa Okuta Elerin ni ilu Akure, ipinlẹ Ondo ni ooru mọju.
Idi ti wọn fi ṣe ikọlu naa ko i tii han si ẹnikẹni, amọ ẹmi ọlọpaa kan lọ si iṣẹlẹ naa.
Ninu atẹjade ti Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo fi lede ni wọn ti ni nkan bi aago kan ooru mọju ni iṣẹlẹ naa waye.
Iwadii ti bẹrẹ lori ikọlu si agọ ọlọpaa – Kọmiṣọnna ọlọpaa Ondo
Wọn ni awọn ọlọpaa naa to wa lakọlakọ nigba ti iṣẹlẹ naa waye ko jẹ ki awọn agbebọn naa raaye wọle sinu agọ ọlọpaa naa.
Lasiko ti wọn koju ibọn si ara wọn ni ọkan lara awọn ọlọpaa naa fi ara gba ọta ibọn, ti o si ku ki o to de ileewosan.
Kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Ondo, CP Oyeyemi Adesoye Oyediran ti paṣẹ iwadii finfini lori iṣẹlẹ naa.
Ọga ọlọpaa naa paṣẹ ki wọn wa awọn ika naa ni awari, ki wọn si fi panpẹ ọba mu wọn.
Bakan naa ni o fi asiko yii rọ awọn eniyan ni ilu lati maṣe mikan, ki wọn si ṣe iṣẹ wọn lai si ipaya nitori ọwọ yoo tẹ awọn ọdaran nipinlẹ naa.












