Bí ìsẹ̀lẹ̀ obìnrin tó jí ọmọ jòjòlò ọjọ́ mẹ́ta gbé ní Ibadan ṣe ṣẹlẹ̀ nìyíí

Aworan obinrin to gbe ọmọ pọn si ẹyin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan yii ko niiṣe pẹlu iroyin yii, ajuwe lasan ni

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria nipinlẹ Oyo ni awọn ti fi panpẹ ọba mu obinrin to ji ọmọ ọjọ mẹta gbe lọ ni ilu Ibadan.

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, DSP Adewale Oṣifẹsọ lo fi idi ọrọ naa mulẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni afurasi naa, Itunu Adepoju to n gbe ni ilu Eko lo ji ọmọbinrin naa lọwọ iya rẹ ni ọṣẹ to kọja.

Iya ọmọ naa ni Monsurat Lateef to n gbe ni agbegbe Itamerin, Ogbere, ni ijọba ibilẹ Ona Ara ni Ibadan.

Bi iṣẹlẹ ijọmọgbe naa ṣe waye...

Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe fi lede Arabinrin Monsurat Lateef lo bi ọ̀mọbinrin ni ọjọ Satide ni agbegbe Mission House, Yahora Faith Mission, Itamerin, Ogbere.

Ni Ọjọ Iṣẹgun to tẹle lo tẹsiwaju lọ si ileewosan Abaemu Genral Hospital, Ona-Ora la ti lọ gba abẹrẹ ajẹsara fun ọmọ rẹ to si ba afurasi naa to ṣe bi ọrẹ si nitori ohun naa wa gba iwosan nibẹ.

Amọ Monsurat ko mọ pe afurasi naa ṣẹ̀ṣẹ bi ọmọ to salaisi ti wọn si ti ran lọ si ileewosan naa lati lọ ṣe ayẹwo rẹ.

Nibi ti wọn ti n sọrọ ni afurasi naa ti sọ fun un pe awọn fẹ wa si ilu Ibadan lati ilu Eko, ti oun si nilo ibi ti oun fẹ ma gbe, ti Monsurat si gbaagbo pe oun yoo ran lọwọ lati wa ile.

Bakan naa ni Monsurat tun ṣeleri pe oun yoo gba ki o sun si ile oun ni alẹ ọjọ naa.

Lẹyin naa ni obinrin naa gba ki o gbe ọmọ rẹ sẹyin, ti afurasi naa si ni oun fẹ lọ gba owo ni POS ti ọkọ afẹsọna ọun fi ranṣẹ si oun.

Lẹyin naa ni afurasi naa di awati, ti iye Monsurat si sọ pe arabinrin naa ti ji ọmọ rẹ gbe lọ.

Atẹjade naa fikun un be iwadii lori iṣẹlẹ naa n lọ lọwọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn n gbe ọrọ naa lọ si ileẹjọ ti iwadii ba ti pari.