A tún fé ṣe àdínkù afẹ́fẹ́ gáásì tí à ń gbé lọ Yuroopu – Russia

Oríṣun àwòrán, Google
Ileeṣẹ Gazprom lorilẹede Russia to n ṣe apinka Gaasi ti kede pe awọn fẹ ṣe adinku afẹfẹ gaasi ti awọn n gbe lọ si ilẹ Yuroopu.
Ileeṣẹ Gazprom ni atunṣe ti awọn n ṣe lọwọ lo fa eyi amọ ajọ iṣọkan yuroopu ni o lọwọ ijọba Russia ninu.
Gasprom ni ida oogun adinku ni yoo ba ipese gaasi ti wọn n gbe lọ si ilẹ Yuroopu.
Amọ ijọba orilẹede Germany ni ko si iṣoro to yẹ ko te ba ileeṣẹ naa ti yoo fi ṣe adinku ipese gaasi to n fun ilẹ Yuroopu.
Eyi yoo jẹko lẹra fun awọn orilẹede ni Ajọ Iṣọkan Ilẹ Yuroopu lati ko gaasi pamọ saaju asiko otutu to n bọ lọna.
Orilẹede Russia lo n pese ida ogoji afẹfẹ gaasi ti wọn n lo ni ilẹ Yuroopu amọ ajọ EU ni Russia n lo ọrọ afẹfẹ gaasi lati ba wọn jagun.
Russia n fi afẹfẹ gaasi ṣe ohun ijagun tako wa ni – Ukraine
Orilẹede Ukraine ti fẹsun kan orilẹede Russia pe wọn n lọ gaasi gẹgẹ bi ohun elo ijagun tako wọn.
Wọn eyi latari igbese ileeṣẹ afẹfẹ gaasi ni ilẹ Russia to ṣe adinku afẹfẹ gaasi ti wọn n gbe lọ si awọn orilẹede ni Yuroopu.
Ukraine ni igbeṣẹ ileeṣẹ Gazprom ti Russia yoo fi iya jẹ awọn eniyan nitori afẹfẹ gaasi ko ni to fun wọn.
Aarẹ ilẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky ni wọn fi afẹfẹ gaasi naa dunkoko mọ ilẹ Yuroopu.
Amọ ileeṣẹ naa ni atun’\se ni awọn n ṣe ni ẹka to n pese afẹfẹ gaasi naa.
Ọjọ mẹwaa ni wọn ko fi gbe gaasi lọ si Yuroopu, ki wọn to bẹrẹ si ni gbe pada lọ ni nkan bii ọjọ marun un sẹyin.
Bakan naa ni wọn fikun un pe igbeṣẹ yii yoo jẹ ki inira de ba awọn ti ko ri ọwọ fi rọ ori, nitori otutu naa yoo ti pọju fun awọn eniyan lasiko otutu to n bọ lọna.












