Ojú gbàmí tì fún un yín, ẹ̀yin asòfin –Aliyu Wabara
Adarí osisẹ orilẹ-ede Naijiria, NLC, Aliyu Wabara ti ní ìtìjú ló jẹ́ fún awọn asòfin láti má wà á ojutuu ti ìyansẹ́lódì ti ASUU gunle lati osu márùn ún sẹ́yìn.

Omoyele Sowore, Shehu Sanni, Biodun Ogunyemi, Emmanuel Osadeke, egbe awon akekọọ Naijiria ati ọpọ ero jade wọde lodi si bi ijọbaBuhari se n wo iyanselodi awon Olukọ Fasiti niran lati osu marun un seyin ni Abuja.
ASUU strike: Ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́ lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà , NLC, gbé ìwọ́de lọ sí ilé igibmọ̀ asofin.
Lara awọn ohun ti awọn olukọ Fafiti ń bèèrè lọ́wọ́ ìjọba ni:
ẹ̀kún owó osù,
àyípadà àti àtúnse sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ Fáfitì, ijọba to wa jake jade orilẹ ede Naijiria.
Sisan owó àjẹmọ́nú awọn osisẹ ẹgbẹ Asuu.
Títẹ̀lé àdéhùn tí ìjọba se pẹlu ẹgbẹ Asuu lọdun 2009
Ki ìjọba tún yọ awọn ọmọ ẹgbẹ́ Asuu kuro nibi ètò IPPIS Integrated Payroll and Personnel Information System abbl.
Awọn nnkan wọnyii lo faa ti ẹgbẹ awọn osisẹ Fafiti se bẹrẹ iyansẹlodi wọn, lati bi osù karun un sẹyin.
Adari ẹgbẹ awọn osisẹ lorilẹ ede Naijiria, Comrade Ayuba Wabba lo dari gbogbo awọn ẹgbẹ osisẹ yooku ninu eto iwọde to waye lonii yii, niluu Abuja.
Iwọde yii to bẹrẹ ni deede aago mọ́kànlá ààbọ̀ (11:30am) lo jẹ asekagba lati fi kadii iwọde ọlọjọ meji ti ẹgbẹ osisẹ gunle.
Ni eyi to waye niluu Abuja .Iwọde yii bẹrẹ ni Unity Fountain to wa niluu Abuja ti wọn si gbee lọ si ile igbimọ asojú- sòfin.

Kini awon Asojusofin sọ fun awon oluwode?
ọ̀kan lara ọmọ ile igbimọ asofin ilu Abuja. James Adisa Owolabi lati ifakọjaye ti ipinlẹ Eko jade ba awon oluwode sọrọ.
O fi da awọn ẹgbẹ osisẹ loju pe awọn asofin yoo pe minisita fun eto ẹkọ, minisita fun eto to rọ mọ ọ̀rọ̀ isẹ lati wa ojutuu si iyansẹlodi ẹgbẹ Asuu, ki awọn akẹkọọ lee pada sẹnu ẹ̀kọ́ wọn.
Kini idi ti NLC fi seto iwode yii?
Bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ awọn osisẹ NLC ti ni ti ijọba ko ba tete da ẹgbẹ Asuu lohun awọn yoo bẹrẹ iyansẹlodi ọlọ́jọ́ mẹta lati fi fa wọn létí.
Awon wo lo tun kopa nibi iwode naa?
Lara awọn to wa nibi iwọde ọhun naa ni Ayuba Wabara, Omoyele Sowore, adari ẹgbẹ awọn olukọ Fasiti,ASUU , ọjọgbọn Emmanuel Osodeke.
Awon mii ni adari ẹgbẹ awọn olukọ Fasiti, ASUU tẹlẹri, ọjọgbọn Biodun Ogunyemi, asoju sofin Abuja tẹlẹri Shehu Sanni, ẹgbẹ awọn osisẹ fasiti, Senior Staff Association of Nigeria Universities (SSANU).
Awon to ku ni awọn Non-Academic Staff Union of Universities, awọn adari ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorilẹ-ede Naijiria, adari ẹgbẹ awọn ọ̀dọ́ ati awọn eniyan pataki lo wa nibi eto iwọde ọhun.
Bakan naa, ni awọn agbofinro, awọn ọlọpaa, awọn ile-isẹ́ aabo ara, aabo ilu, NSCDC, lati mojuto eto aabo.
Ìwọ́de yii tun fa súnkẹrẹ-gbàkẹrẹ awọn ọkọ laarin awọn ojú pópó to wa niluu Abuja.
Wámúwámú ní àwọn ọlọ́pàá dúró nílé aṣòfìn nítorí ìfẹ̀họ́núhàn NLC

Oríṣun àwòrán, Google
Oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, NSCDC lo duro wamuwamu ni ile aṣofin Naijiria lasiko ifẹhọnuhan awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, NLC ni ilu Abuja.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC naa lo n ṣe ifẹhọnuhan lati ṣe atilẹyin fun awọn olukọ ajọ ASUU ti wọn ti wa ni iyanṣelodi fun bi oṣu marun un bayii.
Kaakiri orilẹede Naijiria ni awọn oṣiṣẹ naa ti n ṣe iwọde tako aibikita ijọba si iyanṣelodi naa, eleyii to ti mu ki awọn akẹkọọ joko sile fun ọjọ pipẹ.
Lara awọn to pejọ sibi ifẹhọnuhan naa ni Aarẹ ẹgbẹ Ayuba Wabba; Oludije sipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu AAC, Omoyele Sowore, Sẹnatọ Shehu Sani, Ọjọgbọn Emmanuel Osodeke, Ọjọgbọn Biodun Ogunyemi ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Idi ti awọn ọlọpaa fi pejọ wamuwamu si ibi ifẹhọnuhan
Ọkan lara oṣiṣẹ ọlọpaa to ba awọn oniroyin sọrọ ni awọn wa nibẹ lati da aabo bo awọn eniyan.
Wọn ni awọn wa nibẹ nitori ikọ Boko Haram to n dunkoko mọ awọn eniyan ni ilu Abuja.
‘’A wa nibẹ lati pese aabo to peye fun awọn eniyan ati ohun inu wọn .’’
‘’Ko si idi fun awọn eniyan lati ma a bẹru, nitori ko si wahala kankan to yẹ ko ṣẹlẹ.
Amọ awọn afẹhọnuhan naa yabo ile Aṣofin lati fi aidunnu wọn han.
Bakan naa ni awọn aṣofin ni Ile Aṣofin ti kuro ni ijoko ile, ti wọn si ti lọ si idakọnkọ.

Aliyu Wabara to je olori ẹgbẹ osise sọ pé: A ko ni gbá, kí wọ́n ba ọjọ iwájú àwọn ọmọ wa jẹ́, Wọ́n ti sọ owó naira di yẹ̀yẹ́.
O tun sọ pe: Ti wọn kò bá tètè dá àwọn ASUU lóhùn,a ô gùnlè ìyansẹ́lódì ọlọ́jọ́ mẹ́ta. Bakan naa lo menuba koko pe: Owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ Fásiti ASUU, kò tó bọ́ àwọn ọmọ wọn rara.



Lónìí yìí ni ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà, NLC yóò tẹ̀síwájú nínú ìwọ́de wọ́n, nílùú Abùjá, eyii ti wọn pe ni ‘Mega rally.’
Eléyìí ni yóò jẹ́ àsekágbá rẹ̀, láti sàtìlẹ́yìn fún ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ fásiti, ASUU, látàrí ìyansẹ́lódì ti ẹgbẹ́ ọ̀hún gúnlè láti bí oṣù mẹ́fà sẹ́yìn.
Ana ọjọ Iṣẹgun ni NLC kọkọ bẹrẹ ifẹhonuhan naa lawọn ilu nla kan ni Naijiria bii Eko, Abeokuta, Osogbo, Ibadan ati Akure.



Wọn sọ pe asiko ti to ki ijọba gbe igbesẹ to yẹ lori iyanṣẹlodi awon oluko Fasiti lati oṣu karun un sẹyin. Ose meji ni gbendeke asiko ti wọn fun ijọba Buhari lati yanju ọrọ ASUU.
Wọn sọ pe asiko ti to ki ijọba gbe igbesẹ to yẹ lori iyanṣẹlodi awon oluko Fasiti lati oṣu karun un sẹyin.
Ọsẹ meji ni gbendeke asiko ti wọn fun ijọba Buhari lati yanju ọrọ ASUU.
Ẹwẹ, alaga NLC ti ipinle Eko, Arabinrin Agnes Sessy rọ ijoba apapọ lati tete gbe igbesẹ to yẹ tabi ki wọn maa reti iwọde bii ti #Endsars ti ọdun 2020.












