Lára àwọn ẹgbẹ́ tó létò jùlọ ní Nàìjíríà ni CAN - Tinubu

Oríṣun àwòrán, @Others
Olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Bola Ahmed Tinubu ti júwe ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Krìsìtẹ́nì, CAN, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ tó létò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Asiwaju Tinubu sọ èyí nínú àtẹ̀jáde kan tó ti kí Ààrẹ CAN tuntun, ẹni ọ̀wọ̀ Daniel Okoh kú oríire ìyànsípò rẹ̀.
Tinubu ní kìí ṣe ìgbáyégbádùn àwọn Kristẹni nìkan ni ẹgbẹ́ CAN ń jà fún bíkòṣe ìrẹ́pọ̀ àti ìbágbépọ̀ àláfíà gbogbo ẹ̀sìn.
Tinubu ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà wà ní àkókò tó lágbára tí àwọn kan ń wá ọ̀nà láti dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn pẹ̀lú ìgbìyànjú láti kọ ẹ̀yìn àwọn ènìyàn síra wọn.
Ó fi kun pé tí èrò gbogbo ènìyàn bá ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí gbogbo nǹkan, ohun tó dájú ni pé gbogbo ènìyàn ló fẹ́ láti gbé ní ìrẹ́pọ̀ àti àláfíà.
Bákan náà ló ní inú òun dùn sí gbogbo ìgbésẹ̀ èyí tí CAN ń gbé láti mú kí àláfíà jọba ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Tinubu sọ síwájú pé tí gbogbo ènìyàn bá le máa tẹ̀lé ìrẹ́pọ̀ àti ìṣọ̀kan èyí tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ń bá bọ̀ láìfi ti ẹ̀sìn tàbí ẹ̀yà ṣe, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ma gòkè àgbà.
Nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Daniel Okoh, Ààrẹ tuntun tí CAN yàn fi rọ́pò Supo Ayokunle

Oríṣun àwòrán, Pilot news
Ẹgbẹ́ ọmọlẹyin Kristi, CAN, ti yan alufaa, ẹni ọwọ Daniel Chukwudumebi Okoh, gẹgẹ bi aarẹ tuntun ti yoo rọpo Alufaa Supo Ayokunle.
Akọwe agba fun ẹgbẹ́ naa, Ọgbẹni Joseph Daramola lo kede eyi ninu atẹjade kan n'ilu Abuja, lọjọ Iṣẹgun.
Alufaa Okoh ni oludasilẹ ati alamojuto ìjọ Christ Holy Church,
Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje, ni ipade apapọ ẹgbẹ́ naa yoo waye, nibi ti wọn o ti ṣe ifilọlẹ aarẹ tuntun naa.
Ipade naa ni yoo tun fi opin si saa Alufaa Samson Olasupo Ayokunle, ati awọn ọmọ igbimọ oludari.

Oríṣun àwòrán, Other
Pasitọ Ayokunle ni aarẹ keje fun CAN, to si tun jẹ aarẹ kẹfà fun ìjọ Baptist.
Ọdun 2016 lo de ipo aarẹ CAN, lẹyin ti Ayo Oritsejafor kuro nipo.
O tun pada wọlé saa keji lọdun 2019.
Àwọn nkan to yẹ kí o mọ̀ nípa aarẹ CAN tuntun, Daniel Okoh

Oríṣun àwòrán, West African Pilot
Ọjọ kejila, oṣu Kọkanla, ọdun 1963, ni wọn bi Alufaa Daniel Chukwudumebi Okoh niluu Kano, sugbọn ọmọ bibi ilu Ndoni nijọba ibilẹ Ogba/Egbema/Ndoni, nipinlẹ Rivers ni.
Alufaa Daniel Okoh ti di awọn ipo kan mu
Alaga ajọ Organisation of African Instituted Churches (OAIC);
National President of OAIC (Nigeria) (2005 – 2014);
Igbakeji aarẹ ẹgbẹ́ National Christian Association of Nigeria, CAN, (2007 – 2013) ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa lo wa lara eeyan mẹfa to ṣoju ẹgbẹ́ CAN nibi ipade apero àtúnṣe eto oṣelu ti ìjọba apapọ ṣe agbatẹru rẹ lọdun 2005.
Laarin ọdun 2009 – 2011, ẹni ọwọ Daniel Okoh jẹ ọmọ igbimọ oluṣakoso ajọ itaniji ni Naijiria, National Orientation Agency, gẹgẹ bi aṣoju ẹgbẹ́ CAN.












