Ọlọ́pàá kankan kò láṣẹ láti gbá aráàlú létí, àwọn ohun tó lè lò rèé – Agbẹnusọ ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Google
Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ti kede pe ọlọpaa kankan ko laṣẹ lati digbaju bo araalu lẹnu iṣẹ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Olumuyiwa Adejobi lo fi lede loju opo Twitter rẹ
Adejobi ni ọlọpaa to ba gba oju ara ilu, ti lu ofin ifiyajẹni lọna aitọ.
O ni ko si aṣẹ lọwọ ọlọpaa lati lo igbaju abi fi ẹgba naa araalu.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Awọn ohun eelo ibawi ti ọlọpaa le lo ree...
Agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa naa ni awọn ohun elo wa ti ọlọpaa le lo lati ri pe alaafia jọba lẹnu iṣẹ rẹ.
‘’ọlọpaa ni ohun elo ibaniwi lara rẹ to ba ofin mu kii ṣe igbaju, igbamu abi ki wọn ma a na eniyan.’’
‘’Kumọ (baton), afẹfẹ tajutaju(teaser or spray) nikan ni ọlọpaa ma n lo ni ẹnu iṣẹ.
O fikun un pe o lodi si ofin patapata.
Amọ awọn ọmọ Naijiria to fesi si ọrọ agbẹnusọ naa ni aimoye igba ni awọn ọlọpaa naa ti digba digbamu bo araalu lọna aitọ.
Wọn parọwa si ileeṣẹ ọlọpaa lati gbe ofin kalẹ tako aṣilo agbara awọn ọlọpaa, ki wọn ye lu araalu tabi fi iya jẹ wọn lọna aitọ.












