Ẹ̀gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn olùfẹ̀hónúhàn yabo ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin.

Àwọn olùfẹ̀hónúhàn

Kò dín ní ẹ̀gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn tó ti yabo ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní Baghdad, olú ìlú Iraq.

Àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà ló jẹ́ alátìlẹyìn olórí ẹ̀sìn kan, Muqtada al-Sadr.

Ohun tí wọ́n ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn lé lórí ni bí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀ èdè ṣe fa orúkọ ẹlòmíràn kalẹ̀ yàtọ̀ fún tí Sadr gẹ́gẹ́ bí olóòtú ìjọba orílẹ̀ èdè náà.

Ní orí tábìlì ilé ìgbìmọ̀ náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùn sí, tí wọ́n ń kọrin, tí wọ́n sì tún ń jó.

Púpọ̀ nínú àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí Sadr ló gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò tó wáyé ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún nínú oṣù Kẹwàá ọdún 2021.

Ṣùgbọ́n wọn kò sí nípò nítorí àwọn rògbòdìyàn tó wáyé lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún.

Iraq

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìròyìn ní àwọn ọlọ́pàá yin afẹ́fẹ́ tajútajú sí àwọn tó ń olùfẹ̀hónúhàn náà àti pé kò sí ọmọ aṣòfin kankan lórí ìjókòó nígbà tí wọ́n lọ.

Gbogbo àwọn ààyè tó ṣe kókó ni ilé ìgbìmọ̀ ọ̀hún ni àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà ṣe ìwọ́de wọ̀.

Ẹ̀wẹ̀, olóòtú ìjọba tó wà nípò lọ́wọ́lọ́wọ́, Mustapha Kadhimi tí rọ àwọn tó ń fẹ̀hónúhàn náà láti kúrò nínú ọgbà náà ni kíákíá.

Kí ló fa ìfẹ̀hónúhàn yìí?

Àwọn olùfẹ̀hónúhàn

Láti bí oṣù mẹ́sàn-án ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín àwọn olóṣèlú ní Iraq ní èyí tó ń ṣe ìdíwọ́ fún kí ìjọba pààrọ̀ ọwọ́ ni orílẹ̀ èdè náà.

Sadr jẹ́ alfa ìjọ Shia tó ń gbèrò láti fi òpin sí bí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà àti Iran ṣe ń dá sí ọ̀rọ̀ Iraq.

Ó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò tó kọjá ní orílẹ̀ èdè náà ṣùgbọ́n tí kò ì tíì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nítorí ó ní òun kò lè bá àwọn alátakò òun ṣiṣẹ́.

Bákan náà ni òun àti àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ń tako olùdíje Mohammed al-Sudani gẹ́gẹ́ bí olóòtú ìjọba nítorí pé ó sún mọ́ Ìran.

Ìwọ́de tó wáyé yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tí Iraq ń kojú pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ní epo rọ̀bì tó.

Ní ọdún 2019 ní irúfẹ́ ìwọde ńlá báyìí ti wáyé sẹ́yìn níbi tí àjọ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.

Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ti ní kò sí aburú nínú bí àwọn ènìyàn ṣe ń ṣe ìwọ́de tó bá ti jẹ́ èyí tó wáyé pẹ̀lú àláfíà.