Tala Safwan ọmọ Egypt tí wọ́n mú ní Saudi ní ọ̀rọ̀ tí n bá ọ̀rọ̀ bọ̀ lórí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Tala Safvan
Gbajugbaja lori ẹrọ ayelujara lorilẹede Egypt ni wọn ti fi panpẹ ọba mu ni Saudi Arabia fun ẹsun pe o fi ohun to n sọrọ nipa ibalopọ abo si abo si ori ẹrọ ayelujara.
Tala Safwan to ni ẹniyan miliọnu marun un to n tẹle ni ori ẹrọ ikansiraẹni TikTok, to si tun ni iye eniyan to to 800,000 lori You tube, ni wọn fi ẹsun ọhun kan.
Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede naa ni fidio to fi si ori ayelujara naa le ṣekoba fun ihuwasi awọn eniyan lawujọ.
Amọ arabinrin naa ni kii nkan ti oun n ro ni ọkan niyẹn.
Bi Tala Safwan ṣe n ṣiṣẹ rẹ
Tala Safwan ni o ni irun dudu kekere pẹlu oju to famimọra paapaa awọn ọdọ ni orilẹede naa.
Awọn fidio rẹ ni o ma n niiṣe pẹlu nkan to n ṣẹlẹ ni orilẹede naa, iroyin kaakiri ati awọn ohun ti awọn ololufẹ rẹ ma a fẹran lati mọ.
Iṣẹ rẹ dabi awọn ilumọọka lori ayelujara kaakiri agbaye bii tirẹ
Ọlọ́pàá fi páńpẹ́ ọba mú obìnrin tó fi fídíò ohun tó jọmọ́ ìbálòpọ̀ abo sí abo sórí ayélujára
Amọ eleyii to ṣẹṣẹ ṣe yii ko ba awọn eniyan lara mu.
Ninu fidio naa lo ti n ba arabinrin kan sọrọ̀ to jẹ ọrẹ rẹ ara Saudi to pe wa si ile rẹ.
Amọ awọn oun to bẹrẹ si ni sọ le tunmọ si ọrọ ibalopọ tabi to niiṣe pẹlu rẹ.
Eleyii mu ki awọn eniyan bẹrẹ si ni sọrọ nipa rẹ lori ẹrọ ayelujara paapaa lori Twitter pẹlu Hashtag ‘’Tala Offends Society.’’
Ọlọpaa ti fi panpẹ ọba mu Tala Safwan
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi lede ti wọn ti fi lede pe awọn ti fi panpẹ ọba mu arabinrin kan ti o ṣeeṣe ki ihuwasi rẹ da wahala silẹ
Amọ wọn ko darukọ rẹ.
Ohun ti wọn ṣe ni pe wọn fi fidio naa silẹ ti wọn si safihan oju rẹ amọ ti wọn bo oju ọrẹbinrin rẹ naa.












