Àpẹrẹ ìrẹ́pọ̀ àti ìṣọ̀kan mùsùlùmí àti Krìstẹ́nì là fí hàn ní Ijomu Oro-Venerable tó ṣadura sí ọkọ̀ Ìmáàmù
Aworan to ṣafihan awọn ẹlẹsin meji to jijọ duro sara ọkọ ni awn ọmọ Naijiria n sọrọ lori rẹ loju opo ayelujara.
Ṣugbọn kii ṣe gbogbo eeyan naa lo mọ pato nkan to waye ti Venerable ijọ Kristẹni kan ati Imaamu ilu Ijọmu Oro ni ipinlẹ Kwara ti ṣe n dọwẹkẹ lori ọkọ ti Imaamu ra.
BBC Yoruba tẹsiwajulati t pinpin nkan tiowaye nibẹ la si ti ri aridaju pe lootọ ni Imaamu gbe ọkọ tuintun to ṣẹṣẹ ra lọ sọdọ alagba ijọ Kristẹni pe ko ṣadura si.
Iṣẹlẹ yi ti mu ki ọpọ ọmọ Naijiria maa kan saara si awọn mejeeji pe iru awokọṣe to yẹ re lasiko yi ti ija ẹlẹsinmẹsin ati ẹlẹyamẹya gbode ni Naijiria
A n ṣe ijọsin lọwọ ni Imaamu ṣadede gbe ọkọ wa bawa nile ijọsin
Orukọ Venerable ti ọrọ yi kan ni Ebenezer Oyeleye Oyedalu ti wọn si jẹ oludari ijọ Christ Anglican Church,ni Ijọmu Oro .
Gẹgẹ bi alaye ti o ṣe fun BBC Yoruba o loun kii ṣe ọmọ Ilu Ijomu Oro ṣugbọn lati igba ti iṣẹ Ọlorun ti dari rẹ wa si ilu naa ni irẹpọ ti wa laarin oun ati Imaamu ilu naa.
''Laarọ ọjọ Isinmi to kọja ni nkan bi ago mẹjọ ni mo kọja lẹgbẹ mọsalasi. O jẹ igab akọkọ ti emi ati Imaamu yoo ri ara wa lẹyin ti wọn ti ṣe ọdun tan. O beere pe akoko wo laa pari ijọsin mo si ṣalaye fun. Amọ o ni nkan bi ago mẹwaa loun le wa yọju si mi. Mo ni ko buru''
''Sadede ni a n ṣe ijọsin lọwọ ni nkan bi ago mẹwaa owuro to si gbe ọkọ wa bawa ni ile ijọsin.Nigba ti mo jade si , o ni oun ṣẹṣẹ ra ọkan naa ni oun si fẹ ki n gbaura si.Inu mi dun, mo si gbaura pe ẹmi rẹ ni yoo lo ọkọ naa.''
''Ibẹ la wa tawọn ọdọ ijọ ti jade ti wọn si ya aworan .Mi o mọ pe awọn eeyan tiẹ ti ri aworan naa loju ayelujara.''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kini Imaamu sọ lori iṣẹlẹ yi

Oríṣun àwòrán, Tunde Adewara
Orukọ Imaamu ti o wa ninu aworan taa n wi yi ni Imaam Ibrahim Bashir Adewara oun si ni Imaamu agba ilu Ijomu Oro.
Ninu alaye ree, o ni ohun ti oun ṣe nipa fifi ọkọ naa han Venerable pe ko ṣe adura si kii ṣe nkan to jẹ tuntun nitori awọn ko ṣẹṣẹ maa ba ara wọn ṣe.
''Ki n to ra ọkọ naa ni Venerable ati awọn olori ẹlẹsin mii to jẹ musulumi ati Kristẹni ti n fi adura ran mi lọwọ pe ki Ọlọrun pese ọkọ fun mi.''
''Nigba ti mo si ti wa ra ọkọ naa tan, ṣe ko yẹ ki gbogbo wọn ṣadura si ni?''
Imam Adewara sọ pe ibaṣepọ alaafria lo wa laarin awọn ẹlẹsin gbogbo ni Ilu Ijomu Oro ati pe bẹẹ lawọn ṣ n ṣe ni gbogbo Oke Mesan Oro patapata.
O fi kun ọrọ rẹ pe ohun ti ẹsin kọ oun ni pe ki oun ṣe daada si alabagbe oun ko si si iyasotọ laarin Kristẹni ati musulumi ninu alabagbepọ.
Lafikun ọrọ rẹ, o ni eleyi to dara ju ni pe ki awọn olori ẹlẹsin fi apẹrẹ daada lelẹ fun awọn to n tẹle wọn ati pe ''awọn oloṣelu lo de ti wọn mu iyapa wa laarin gbogbo wa. Ninu ilu wa,musulumi ati Kristẹni ọkan naa ni gbogbo wa.''














