Ó kéré tán ènìyàn 33 kú lásìkò tí ọkọ̀ bọ́ sínú omi

Oríṣun àwòrán, Google
O kere tan eniyan mẹtalelọgbọn ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti ọkọ akero to gbe awọn eniyan jabọ sinu omi lẹyin to kuro lori afara.
Ijọba orilẹede Kenya ni eniyan mẹwaa lo jajabọ ninu iṣẹlẹ naa.
Ọkọ naa ni wọn ni ohun rin irinajo lati ilu Meru si ilu eti omi Mombasa, ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.
Ijanu ọkọ to da iṣẹ silẹ lo fa ijamba ọkọ
Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii fihan pe ijanu ọkọ lo kọ lati ṣiṣẹ to si fa ijamba ọkọ naa.
Nibayii, wọn ti bẹrẹ si ni wa awọn ti wọn padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ naa, to si ṣeeṣe ki iye awọn eniyan to ku ninu iṣẹlẹ naa pọsi.
Awọn aworan to wa lori ẹrọ ayelujara safihan bi ọkọ naa ṣe run jegejege, ti ori ọkọ naa si yọ danu pẹlu ohun ini awọn ẹrọ inu ọkọ si fọnka.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni ọkọ akero naa lo dede kuro ni oju ọna afara to wa to si bọ sinu odo Nithi River to to iwọn ogoji mita.
Iṣẹlẹ naa jẹ ọkan ninu awọn ijamba ọkọ to ti ṣẹlẹ lorilẹede naa, to mu ẹmi awọn eniyan lọ.












