Tinubu leè sọ Nàìjíríà di Olú-ìlú ọrọ̀ ajé lágbàáyé, ìdí rèé – Adárí àwọn obìnrin APC

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu Twitter
Adari ẹgbẹ awọn obinrin to wa ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Arabinrin Betta Edu ti fi ogun oludije ẹgbẹ wọn fun ipo aarẹ gbari pe oun lo ni agbara lati yi irawọ Naijiria pada si orilẹede ti yoo jẹ ọga gbogbo orilẹede ọlọrọ aje jakejado agbaye.
Betta fi eyi lede nilu Abuja lasiko ti awọn obinrin to jẹ ọdọ lẹgbẹ APC n ṣepade niluu Abuja nibi to n sọ idi to fi yẹ ki wọn tete gbaruku ti Tinubu fun ọdun 2023.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, Tinubu ni oludije to dantọ ju lori iwe akojọpọ gbogbo awọn oludije fun ọdun 2023 to jẹ pe oun lo lee tun Naijiria to.

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu Twitter
Nibi ipade ọhun lo ni ki awọn obinrin ẹgbẹ bẹrẹ si ni lọ lati ojule si ojule maa ṣe ipolongo fun Tinubu.
“Asiko ti to lati gbagbe gbogbo ayọnusọ awọn kan ati yẹyẹ ti wọn n ṣe, ki a si bẹrẹ si ni lọ kaakiri ojule si ojule, ile itaja si ile itaja”.
Betta gba awọn akẹgbẹ rẹ to jẹ ọdọbinrin nimọran lati lo anfani awọn obinrin ti wọn mọ ati oju opo ayelujara wọn fi ṣiṣẹ fun Tinubu.
O ni toripe awọn ni ero rere o si tun da awọn loju pe Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lo le tun Naijiria to.
“O da wa loju pe bi Asiwaju Bola Tinubu ba le tun ipinlẹ Eko to, Eko to pọ ju awọn orilẹede kan lọ pẹlu o le ni eeyan miliọnu ogun to n gbe nibẹ, o lee tun Naijria ṣe”.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Arabinrin Betta tun fi ọwọ sọya loju awọn akẹgbẹ rẹ pe bi Tinubu ba lee sọ ilu Eko di olu ilu ọrọ aje fun Naijiria, daju daju o lee sọ Naijiria di olu ilu ọrọ aje ni agbaye.
“Ẹ ma jẹ ki ariwo ọja ori ayelujara ṣi yin lọkan, dipo bẹẹ, ẹ koju mọ iṣẹ ati aṣeyọri ti ẹ fẹ ri”.















