Kà nípa bí adití-afọ́jú yìí ṣe di ìlúmọ̀ọ́ká lórí ètò ẹ̀kọ́ àwọn tó ní ìpèníjà ara

Aworan Hellen Keller

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi eeyan ba ti n fọkan ba ọrọ to niṣe pẹlu awọn to ni ipenija ẹkọ bọ, yoo ṣoro ko ma ti gbọ orukọ arabinrin kan ti wọn n pe ni Hellen Keller lagbaye.

Lati nkan bii ọdun mejilelọgbọn, oṣu Keje ọdun ni orileede Amẹrika jẹ oṣu kan pataki lati igba ti wọn ti buwlu ofin awọn to ni ipenija ara lọjọ Kẹrindinlọgbọn ọdun 1990.

Lọdun taa n wi yii ni ilu Boston lorileede Amẹrika di ilu akọkọ ninu itan to ṣe iwọde ajọdun awọn to ni ipenija ara.

Lati igba naa awọn ilu mii naa ti n ṣe ayẹyẹ yi to si ṣepe gbogbo rẹ ko ṣẹ lẹyin gbigbe oriyin fun ipa ribi ribi ti Hellen Keller ko nipa ẹkọ awọn to ni ipenija.

Ajọ ilera lagbaye WHO sọ pe o fẹ ẹ to eeyan to le ni biliọnu kan lagbaye to n koju ipenija ara kan tabi omiran.

Ireti wa pe iye awọn wọn yi yoo lekun si pẹlu bawọn to n darugbo ṣe n pọ si.

Bo tilẹ jẹ wi pe ibaṣepọ wa laarin aini ati ipenija ara, kii ṣe gbogbo awọn to wa nipo aini lo ni deede ipenija ara .

Ibi ti eeyan ba n gbe ati iru anfaani itọju ti iru ẹni bẹẹ ba ni ni yoo ṣe atọn iru inira ti wọn yoo koju.

Lasiko yi tawọn eeyan lagbaye n ṣe iranti Hellen Keller afoju-aditi obinrin ilumọọka tawọn aarẹ Amẹrika ti n tẹti si ọrọ rẹ lati bi ọgọta dun sẹyin,ki la mọ nipa obinrin yi ati pe iru ipa wo lo ko nidi ẹkọ awọn to ni ipenija kan tabi omiran.

Ta ni Hellen Keller?

A bi Helen Adams Keeler lọjọ Kẹtadinlọgbọn dun 1968 ni ilu Tuscumbia, Alabama, ni Amẹrika to sijade laye lọjọ Kini oṣu Kẹfa ọdun 1968 ni Westport, Connecticut,Amẹrika.

Nigba aye rẹ, o jẹ ọkan pataki ninu awọn ilumọọka onbinrin lagbaye.

Onkọwe ni o jẹ, ti fiimu kan ti wọn gbe jade nipa igbesi aye rẹ si gba ami ẹyẹ Oscars meji.

Koda awọn aarẹ Amẹrika a maa kan si ti wọn a si maa gbọ amọran rẹẹ fun nkan to le ni ọgọta dun.

Helen Keller nigba to wa ni ọmọ ọdun meje

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nigba ti Keller wa ni ọmọ ọdunkan abọ,aarẹ deba ti eleyi si mu ki o padanu oju iran ati ọrọ gbigbọ.

Alexander Graham Bell jẹ ọrẹ awọn obi rẹ.

Lọjọ kan to ṣe abẹwo si wọn to si ri Hellen, o fi ranṣẹ si olukọ ẹni ogun ọdun kan iyẹn Ann Sullivan to wa ni aayẹ ikẹkọ fawọn to ni ipenija oju, Perkins Institute for the Blind eyi to wa ni Boston.

Nibẹ ni Hellen Keller ti bẹrẹ si ni kẹkọnipa fifi wọ kan awọn nkan ti yoo si maa fi ika rẹ kọ ati ka orukọ wọn sita nipa patako ti olukọ rẹ ṣeto.

Lọjọ alakọkọ to bẹrẹ si ni kọ ọrọ, ọrọ ọgbọn ni a gbọ pe o kọ.

Keller kẹkọ ni ibudo yi debi pe ko fẹ ẹ si eeyan kankan to ni ipenija oju ati igbọrọ to ni iru imọ to ni.

O ba debi pe o bẹrẹ si ni kọ iwe nipa ipenija airina ti ọpọ nigba naa ko mọ pato nkan to n fa a.

Helen Keller ati olukọ rẹ nigba to wa lọmọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Helen Keller ati Graham Alexander Bell

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nigba ti Keller jade laye lẹni ọdun mẹtadinlaadọ́run ni ọjọ Kini oṣu Kẹfa ọdun 1968, ohun ti wọn kọ sori saare rẹ ni ''o gbọ, bẹẹ lo si riran pẹlu iwoye to kọja ti ẹgbẹ''.

Ninu ọrọ ti Keller fun ara rẹ sọ, o ni ''Mi o ki n saba ronu nipa awọn ipenija mi bẹẹ kii mu mi banujẹ.''

Ile itọju ti wọn sọ lorukọ rẹ lati ọdun 1915 ṣi n pese itọju fawọn to ni ipenija irina ati eleyi to n fa oju fifọ.

Lọdun 1964, aarẹ Lyndon Johnson fi ami ẹyẹ da Helen Keller lọla ni imoore apẹrẹ akinkanju ati ifarajin to ṣafihan.

Kaakiri agbaye loni, Helen Keller jẹ awokọṣe fawọn ọmọde pe ko si nkankan ti wọn ko le ṣe lopin igba ti wọn ba ti fọkan si.

Ni olu ilu ilẹ Amẹrika, wọn mọ ere Keller nigba to wa ni ẹni ọdun meje si ọkankan ibi ẹrọ omi to ti kọkọ kọ ọrọ akọkọ rẹ.