'Mo pa òkìkí tì láti ṣe iṣẹ́ agbálẹ̀ àti ọmọ ọ̀dọ́ ní UK nítorí ọmọ'

Oríṣun àwòrán, Sola Sobowale
Agba oṣerebinrin, Sola Sobowale, ti sọ idi to fi pa iṣẹ tiata ti fun bi ọdun mẹẹdogun, lasiko ti ogo rẹ n buyọ.
Ni nkan bi ọdun 2000 ni Sobowale deedee di awati lagbo tiata , ti ọpọ ololufẹ rẹ si n wadii nkan to ṣẹlẹ si.
Iroyin ti ẹ sọ nigba naa pe o gbe oogun oloro ni orilẹ-ede Saudi Arabia, ti wọn si ti bẹ ori rẹ lẹyin idajọ iku ti wọn ṣe fun nibẹ.
Amọ nigba to n sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu agbohunsafẹfẹ, Chude Jideonwo, ogbontagi oṣerebinrin naa sọ pe, oun fi okiki ati igbe aye irọrun silẹ ni Naijiria fun ọdun mẹẹdogun, lati le ṣe iya fun awọn ọmọ oun to n kawe ni orilẹ-ede United Kingdom.
Sobowale ṣalaye pe oun ti de ipo giga lẹnu iṣẹ tiata, debi pe oun n ri to miliọnu marun-un Naira ni oṣooṣu, ki oun to pa gbogbo rẹ tì lati ma a ṣe iṣẹ agbalẹ nilu oyinbo.
“Oriṣiriṣi iṣẹ bii ilẹ gbigba, alase, ati abani tun ile ṣe ni mo ṣe ni England, lati le ma a pa Pọun meje aabọ ni wakati kan.’
O ni abẹwo kan ti oun sẹ si awọn ọmọ oun nilu England ni asiko kan, ni oun ṣe akiyesi pe awọn ọmọ naa nilo amojuto ìyá, eyi to mu ki oun pinnu lati pa okiki ti.
Arabinrin Sola Sobowale sọ pe oun mọ pataki ẹkọ ninu igbeaye ọmọ, gẹgẹ bi ogun rere ti eeyan le fun wọn.

Oríṣun àwòrán, Sola Sobowale
“Nitori aiṣedeede eto ẹkọ ni Naijiria, paapaa nitori iyanṣẹlodi awọn olukọ fasiti, lo jẹ ki n ko awọn ọmọ mi lọ si fasiti nilu ọba.
‘Mo fi wọn sile ẹkọ, mo si pada si Naijiria. Ṣugbọn, nigba ti mo pada lọ wo wọn lẹyin oṣu diẹ, iwa ati iṣesi wọn ti yatọ si igba ti mo ko wọn lọ.
Nitori naa ni mo ṣe pinnu lati pa iṣẹ tiata ti, ki n le raaye mojuto wọn, ki wọn o ma ba ya iyakuya.’
Oṣere naa ni oun dupẹ pe awọn ọmọ naa ti di olorire lonii. O ni koda, awọn ọmọ naa lo rọ oun lati pada si idi iṣẹ tiata ti oun fẹran lati ma a ṣe, pẹlu imoore si itọju ti oun fun wọn.
Sola Sobowale sọ pe ọpọlọpọ awọn olulufẹ oun lo ma n ya lẹnu, nigba ti wọn ba ri oun nidi iṣẹ ẹgbin nilu England, ti wọn si maa n beere nkan to sun oun de ibẹ.
O ni ṣugbọn oun maa n jẹ ko ye wọn pe ole nikan lo bọmọ jẹ.
Nkan mii to yẹ ki o mọ nipa Sola Sobowale
Ẹni ọdun mejidinlọgọta ni Sola Sobowale.
Ọdun 2016 lo pada si idi iṣẹ tiata, lẹyin ọdun mẹẹdogun to fi pa iṣẹ naa ti.
O si ti n ṣiṣẹ tiata fun bi ọgbọn ọdun o le.
Ṣaaju ko to di gbajumọ, o kopa ninu awọn ere bi The Village Headmaster, Mirror in the Sun, ati Asewo to re Mecca, Ohun ọkọ sọ mi da, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ipa to ko ninu ere ọlọsọọsẹ, Super Story, gẹgẹ bi Toyin Tomato ninu ere naa ti wọn pe akọle rẹ ni Oh Father, Oh Daughter’, ldun 2001, lo kọkọ sọ ọ di olokiki.
Abẹ iṣakoso Adebayo Salami ‘Oga Bello’ ni Sobowale ti bẹrẹ ere tiata.
Lati ọdun 2016 to ti pada si idi iṣẹ tiata, o ti kopa ninu awọn sinima olokiki bi ‘Wedding Party ati King of Boys.
Ninu oṣu Keje, ọdun 2022, o kede pe oun n kopa lọwọ ninu sinima kan ni orilẹ-ede India.












