Àlàyé lórí Adijat Adenike Olarinoye, ọmọ Nàìjíríà tó gba góòlù àkọ́kọ́ ní ìdíje Commonwealth Birmingham 2022

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọ Naijiria to kopa ni idije irin gbigbe, Weightlifting oni iwọn 55kg, Adijat Adenikẹ Ọlarinoye ti gba goolu akọkọ fun orilẹede Naijiria nibi idije ere idaraya Commonwealth games to n lọ lọwọ nilu Birmingham, lorilẹede England.
Iwọn irin ti apapọ rẹ jẹ iwọn kilogiramu mẹtalenigba, 203kg ni Ọlarinoye gbe lati gba ami ẹyẹ goolu ni idije irin gbigbe oni iwọn kilogiramu marundinlọgọta, 55kg.
Ni ẹka iringbigbe yii to jẹ Snatch, iwọn mejilelaadọrun kilogiramu, 92kg lo gbe, iwọn kilogiramu mọkanlalaadọfa, 111kg lo gbe ni ipele Claen and jerk, ti apapọ gbogbo rẹ fi ku si iwọn kilogiramu mẹtalenigba, 203kg.
Agberingbayi lati orilẹede India, Bindyarani Devi Sorokhaniban lo gba ami ẹyẹ fadaka ti agberinjẹun ọmọ orilẹede England, Fraer Morrow gba ami ẹyẹ baba.
Ariwo ayọ nla lo sọ ni ibudo ifiniwọsi awọn ikọ elere idaraya Naijiria nibi idije ere idaraya naa lẹyin ti ọgbogbo awọn agberin yoku ti Naijiria ko lọ sibi idije ere idaraya Commonwealth Games naa kuna lati kogoja.
Ireti ọpọ ọmọ Naijiria bayii ni pe awọn elere sisa ti Naijiria ko lọ sibi idije ere idaraya naa yoo ta biọ̀biọ nigba ti asiko ba to fun awọn idije ere sisa gbogbo.

Oríṣun àwòrán, screenshot
Ta ni Adijat Adenikẹ Ọlarinoye?
Ọmọ ọdun mejilelogun ni Adijat Adenikẹ Ọlarinoye gẹgẹ bi akọsilẹ to wa lọwọ awọn alakoso ere idaraya Commonwealth Games loju opo itakun agbaye Birmingham 2022 .
Ni ọjọ kẹrinla oṣu keje ọdun 1999 ni wọn bii lẹkun iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria.
Ṣaaju akoko yii, ami ẹyẹ mẹta ọtọọtọ ni Ọlarinoye gba fun Naijiria nibi idije ere idaraya ilẹ adulawọ, African Games to waye lorilẹede Morocco ni ọdun 2019 .

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lasiko idije ere idaraya naa, o gba goolu kan ni idije irin gbigbe oni iwọn kilogiramu marundinlọgọta, 55kg ki o to tun lọ gba ami ẹyẹ goolu miran ni ipele Clean-jerk ti idije irin gbigbe oni iwọn kilogiramu marundinlọgọta, 55kg.
Bakan naa lo tun gba ami ẹyẹ fadaka ni idije ere idaraya naa.
Bakan naa ni Ọlarinoye tun gba ami ẹyẹ goolu ni idije agbaye fun irin gbigbe, International Weightlifting Federation World Championship, to waye ni ilu Tashkent lorilẹede Uzbekistan ọdun 2021.












